Temitope Bolugbe
Ida emi ara eni legbodo ti di gbomo gbomo laarin awọn ọdọ ode òní, o sí je ọnà kán tó ya sí ikú.
Gege bí àjọ eleto ìlera l’agbaye (WHO) se sọ, o jẹ ọnà kàn gbòógì tó n ṣokunfa ikú láàrín àwọn ọmọ ọdún marundinlogun sí ọmọ ọdún mokandilogbon l’agbaye ní ọdún 2019.
Ní k’ọpẹ k’ọpẹ yìí, ní akẹkọ kàn tó wà ní ìpele akọkọ ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga fasiti ìpínlè Òsun, Salako Treasure, gb’emi ara rẹ nípa lílò nkan iseku pani lẹyìn ìgbà tí irẹwẹsi gba ọkàn rẹ.
Bakanna, ọkùnrin kan tí o jẹ ọmọ ọgbọ̀n ọdún, Usman Sani náà d’ẹmi ara rẹ legbodo ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ tí Babura ní ipinlẹ Jigawa.
Olóògbé náà ní ìròyìn n so pé o pokun so.
Ìròyìn tún tan nipa ti ọmọbìrin ajagun ojú òfurufú tó n ṣiṣẹ ní ilu-eko, ení ti wọn bá òkú rẹ ni ile’gbe rẹ , nibi tó ti pokunso ní ibùdó àwọn ọmọ ogun ojú òfurufú to wà ní Ikeja, ni ìlú Èkó.
Bí o bá ṣe opelope ọkan lára àjọ tó n dènà ìṣẹlẹ pajawiri ní ipinlẹ Èkó, bí ọkunrin ẹni ọdún meta-din-laadorin kan náà o bá ti gb’emi ara rẹ niyen nigba to gbìyànjú láti fo sinu òkun.
Ọkùnrin nà ṣé lalaye pé òun gbìyànjú láti gb’emi ara òun nítorí ọpọlọpọ ipenija èyítí tó n ba oun finra, to sì tí mùú òun’ ta awọn dukia rẹ bíi ilé, ilẹ ọkọ, ṣugbọn towó náà kò tán gbogbo ìṣòro rẹ.
Nigba to n gbé ọrọ yí yẹwo, onimọ nípa èrò ọkàn, ọmowé Oluwafisayo Adebimpe ṣàfihàn àwọn okùnfà dídá èmi ara ẹni legbodo leleyii ti o le jẹ aibori awọn idojukọ boya nínú ilé tàbí lẹnu iṣẹ.
“Awọn ènìyàn kò rówó ná, ṣe bale’le tí’yawo bèrè owó oúnjẹ tàbí ìyále’le tí kò rise se, tàbí ẹni tó n w’oju ọmọ tí kò bímọ , tabi ẹni tó jáde ilé’we gíga tí kò rise, tàbí ẹnití àjálù ibí re lu, ti wọn gb’owo rẹ lọ tàbí tí ile-ise jona”
Ewe, onimọ nípa èrò ọkàn náà wà gba awọn ẹbi, ara, ọrẹ àti ojúlùmò níyànjú láti joyè ojú lalakan fí n ṣorí ati pé kí wọn gbaruku ti awọn ènìyàn to wa layika wọn, ti wọn n la ìṣòro koja, tàbí àwọn tí wọn bá ti fa sẹyìn tàbí ṣe ainife sí àwọn nkán tó n lọ láwùjọ wọn.
Awọn ara ìlú Ìbàdàn náà fí èrò wón hàn lórí ìdí tí àwọn ènìyàn fi máa n d’ẹmi ara wọn legbodo.
“Ti ìjọba ba pèsè iṣẹ, ti awọn ènìyàn bá rise ṣe, awọn ènìyàn kò ní ronú pé àwọn fẹ pokunso”
“Ti eniyan ba lọ kajọ, èrò k’ero má wá ṣọkan èèyàn”
Àwọn ènìyàn náà gbà awọn tó n kojú irú ìṣòro bẹẹ láti wá ìrànlọ́wọ́ àwọn onímọ̀ nipa ẹrọ ọkàn, dokita nipa ìlera àti ẹni tí wón f’ọkan tan láti dènà awọn iṣẹlẹ to lè gb’emi wọn.
Bakanaa, Onimọ nípa èrò ọkàn , ọmowé Oluwafisayo Adebimpe, ni láti dẹ́kun dídá èmi ara ẹni legbodo, awọn ti ọrọ kàn yii, ní láti gba amoran lọdọ awọn tó mọ nípa èrò ọkàn fún ìtọ́nisọ́nà.
Subscribe to our Telegram and YouTube Channels also join our Whatsapp Update Group