Ijoba Ipinle Ogun ti fi ipinnu re han lati mu atunto to wuyi de ba eka irin ajo afe atawon gbongan asa ibile pelu eron gba lati je kowo to nwole si akoto oba nipinle ohun ko tubo rugoogo sii.
Alamojuto foro asa ati irin ajo afe nipinle Ogun Arabinrin Motunrayo Adeleke Oladapo lo siso loju oro oun lakoko too nforowero pelu akoroyin ileese Radio Nigeria nilu Abeokuta.
Arabinrin Motunrayo Oladapo eni to salaye pe, eleda fi opolopo ibudo irin ajo afe jinki ipinle Ogun bii, gbongan asa june 12, Ori Oke Olumo ati ibudo iyawe kawe Olusegun Obasanjo.
O salaye siwaju pe, akitiyan ti nlo lowo lati mu atunto to loorin ba eka irin ajo afe nipinle naa.
Arabinrin Oladapo tenumo pe, ipinle Ogun lo nle waju ninu awon ipinle gbogbo leka eto asa,paapajulo nidi ipese aso adire.
Nigba to nsoro lori ayajo asa lagbaye fun ti Odun yi, alakoso ro eka aladani lati fowosopo pelu ijoba Ipinle lati mu eka yi dun wo fun awon araalu.
O tun woye pe, irufe igbese oun,yoo je ki awon aralu ni ife sawon ibudo irin ajo afe nipinle naa ati pe yoo tun ni ipa to dara lori oro aje ipinle naa.
Olukemi Ogunkola
Subscribe to our Telegram Channel and join our Whatsapp Update Group