Ní itesiwaju ètò ìwóde tégbé òsìsé NLC gùnlé yíka orilede Nigeria, èyí tó ti wo ojó kejì bayii, Egbé náà atawon akegbé rè ti wode yíká ìlú Abuja loni.

 Ìròyìn sopé, lati nnkan bi ago méje òwúrò Òní lawon òsìsé ti peju- pese si unity Fountain feto ìwóde náà.

Níbáyìnáá, ètò àbò ti gbóná girigiri, ni tìbú- tòòòró ilè Asòfin àpapò ilè yí nilu Abuja, láti le pinwó ìwà jàgídí-jàgan to se e se ko rápálá wonú ìwóde Egbé NLC.

Akòwé àgbà Egbé NLC nílè yí, Ògbéni Emmanuel Ugboaja, sàlàyé pé ètò ìwóde náà lo n wáyé láti Fi sàtìleyìn fun ìyansélódì Egbé Asuu to nlo lówó, èyí tí won Fi gbe gbogbo àwon ilè Èkó gíga fásitì to n be nílè yí tìpa.

Ìwóde to wáyé lánàá ode yí, lawon ìpínlè kan, lo nope àkíyèsí ijoba àpapò si ìyansélódì olojo gbōoro tégbé Asuu gùnlé.

Ò tile lósù márùn-ún bayii, ti Egbé àwon olùkó lawon ilè Èkó gíga fásitì ilè yí atawon Egbé mín -ìn torokan leka ètò Èkó, tíwón ti gùnlé ìyansélódì, Lori èsùn bijoba àpapò se kùnà láti mu àdéhùn rè se fáwon Egbé náà.

Folakemi Wojuade 

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *