Àjọ ton mojuto idagbasoke eto ìlera alabode nipinle Ogun pẹ̀lú ifowosowopo ìgbìmò tó ń risi ọrọ ìlera ojú nipinle náà tí sàgbékalè ètò ayẹwo ojú lofe fáwọn onimoto, ero àtàwọn aladani láwọn ibùdóko jákèjádò ìpínlè náà gẹ́gẹ́bí ara eto ton sàmìń ayajo ọjọ́ iriran tóko lọ́dún yi.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àkòrí todun yi, tii se “nifẹ ojú rẹ, doola ẹ̀mí”, nibi ètò náà tó wáyé nilu Abeokuta, alága ẹgbẹ́ àwọn olùtọ́jú ojú eka tipínlè Ogun  Dókítà Oladapo Awodein ṣàlàyé pé igbelewon tí fihàn pé bí idà lọ́nà adota ìjàmbá ọkọ̀ ton wáyé je nípasẹ̀ airíran, idi niyi tó lómú ṣe kókó láti dojú kọ àwọn onímòto.

Nínú idasi alaga ẹgbẹ́ àwọn onímòto Igun Road Transport Employees Association of Nigeria ní Kútò, Olóyè Lanre Ladipo gbóríyìn fún ìjọba ìpínlè Ogun ló rii mímú ìtọ́jú ohun àbò àwọn onímòto lọkúkúndun pẹ̀lú ríro àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ẹ láti máa ṣètọ́jú ojú wọn boseto.

Alamu/Olaopa

Subscribe to our Telegram Channel and join our Whatsapp Update Group

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *