Àwọn iléékọ alákọbẹ̀rẹ̀ àti girama tó jẹ́ taládani àti tìjọba nípinlẹ̀ Ọyọ wọlé padà fún sáà ètò ẹ̀kọ́ tuntun lẹ́yìn ìsinmi ọlọ́sẹ̀ mẹ́fà.
Àwọn akọ̀ròyìn wa tí wọ́n lọ káakiri ìlú Ìbàdàn láarọ òní, jábọ̀ pé, láti bí aago méje láarọ òní ni wọ́n ti ńríì àwọn akẹ́kọ na tí wan ń lọ sílèwé wọn.
Lára àwọn iléẹ̀kọ tí àwọn akọ̀ròrìn wa déè, ni Àpáta Grammer School, Logudu, Government College, Ìbàdàn, Olúyọ̀lé High School ní Ring-Road .
Olùkọ́ àgbà ní Àpáta Grammer School arábìnrin Esther Okundayọ rọ́ọ̀ àwọn òbí tí àwọn ọmọ nílò fún ètò ìkẹ́kọ.
Lára àwọn olùkọ́ na, bí arábìnrin Olufẹmi Dele, arábìnrin Modupe Ogunsẹyẹ àti Victoria Adetẹju sọ pé, àwọn tí múráà lẹ̀ fún sáà tuntun tó bẹ̀rẹ̀ lóni.
Àwọn akẹ́kọ na sọ pé, inú àwọn dùn láti padà sílèèwé, wọ́n sì dípẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà fún àwọn ohun tó ti pèsè fún wọn fún ìkọ́nilẹ́kọ.
Kemi Ogunkọla/Osamudiamen Idemudia