Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọyọ ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sáwọn olùgbé láwọn agbègbè tí ẹ̀kún omin ti ńsọsẹ́, láti kúrò níbẹ̀ náà láti dènà lílúgbàdì ẹ̀kún omi, bí ìjọba se ńgbé ìgbésẹ̀ láti pinwọ́ ẹ̀kún omi láwọn agbègbè náà.
Alákoso fọ́rọ̀ àyíká àtàwọn ohun àlùmọ́nì, ọ̀gbẹ́ni Kẹhinde Ayọọla, sọ èyí lásìkò tó sàbẹ̀wò sáwọn agbègbè kan tẹ́kun omin ti sọsẹ́.
Alákoso náà kò sài tún gbàwọn olùgbé láwọn agbègbè náà níyànjú láti dẹ̀hìn nídi, ìgbésẹ̀ tó lè dènà lílọ geere lógúsàn omin, tósì fọwa ìdánilójú sọ̀yà pe ìjọba yóò gbe ìgbésẹ̀ láti dènà lkún omi.
Kẹmi Ogunkọla/Iyabo Adebisi