Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọsun ti sèkìlọ̀ fáwọn ilé-ìwé alákọbẹ̀rẹ̀ àti ti giramma láti máse táà tàbí pín asọ ilé-ìwé fáwọn akẹ́kọ lágbègbè wọn, pẹ̀lú bí ìgbésẹ̀ pípadà sí asọ ilé-ìwé titẹ́lẹ̀ yóò se bẹ̀rẹ̀ ni sáà ètò ẹ̀kọ́ 2020/2021.
Sáàjú ni ìjọba ìpínlẹ̀ náà ti kéde pé kí gbogbo ilé-ìwé padà sí asọ ilé-ìwé tíwọ́n nló tẹ́lẹ̀ sáàjú asọ kan soso fún gbogbogbò.
Alákoso fọ́rọ̀ ìròyìn àti ìlanilọ́ọ̀yẹ̀, arábìnrin Funkẹ Ẹgbẹmọde sọ́di mímọ̀ pé, àwọn asọ ilé-ìwé ni yóò jẹ́ títà láwọn ọja ojútáàyé tósìjẹ́ pé, àwọn aránsọ ìpínlẹ̀ náà ni yio pèsè rẹ̀.
Arábìnrin Ẹgbẹmọde sàlàyé pé ìjọba tíì fààyè ọ̀sẹ̀ méjì sílẹ̀ fáwọn akẹ́kọ láti tẹ̀lé òfin náà ni sansan.
Ajadosu/Idogbe