Ijoba Ipinle Oyo ti f’owo si sisan owo to je billion mejo naira fun Ijoba Ipinle Osun, gegebi ara igbese ti won fenuko le lori, lati le je ki ile eko giga varsiti Ladoke Akintola, LAUTECH di ti Ijoba Ipinle Oyo nikan soso.
Alakoso f’oro eto Eko ati Imo Ijinle Science, Ogbeni Olasunkanmi Olaleye lo je koro yi di mimo l’asiko to n baa won akoroyin soro, leyin ipade alase nilu’Badan.
Ogbeni Olaleye so pe owo ohun ni won yoo san l’aarin odun meta, pelu alaye pe billion kan naira, ni yo je sisan larin osu kini si ikejila odun 2021 ta wa yi.
Iyabo Adebisi/Ololade Afonja