Yoruba

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn, ọmọọba Dapọ Abiọdun ti fọwọ́ ìdánilógú sọ̀yà fáwọn ẹ̀yà min-in tó ńgbé nípinlẹ̀ náà pé, ètò àbò tó múná dóko yóò wà fẹ́mi àti dúkia wọn.

Gómìnà Abiọdun tó fọwọ́ ìdánilójú yíì sọ̀yà lákokò tó ń gba Emir tìlú Kano, Mallam Aminu Bayero lálejò lafìsì rẹ̀, sọ pé, àbò ẹ̀mí àti dúkia wọn ló se pàtàkì gẹ́g báwọn ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ náà.

Ó sàlàyé pé, ìgbésẹ̀ mímú ìdàgbàsókè bá orílẹ̀dè kó lè yá kánkán tí kò bá sí ìlọ́wọ́sí àwọn ẹ̀yà min-in tó ńgbé nípinlẹ̀ náà.

Gómìnà Abiọdun wá sèlérí pé, ìsèjọba òun yóò sàmúlò ìmọ̀ràn tóbá àláyé náà fún wọn lórí bájọsepọ̀ tó dánmọ́rán yóò se wà láàrin àwọn èèyàn tó ń gbé nípinlẹ̀ Ògùn.

 Nígbà tó ń fèsì Emir tìlú Kano, Aminu Bayero sọpé, àjọsepọ̀ tó dánmọ́rán láàrin àwọn ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yóò mágbege tí kò lẹ́gbẹ́ bá ìdàgbàsókè orílẹ̀dè yíì.

Ajibikẹ/Wojuade