Yoruba

Ijoba Ipinle Ekiti ti fagile eto isin apapo adura to saaba maa n waye lojo ise akoko ni gbogbo odoodun.

Gege bi atejade t’Alakoso feto iroyin, Ogbeni Akin Omole fisita so wipe, igbese naa lo waye lati fi dena itankale kokoro arun corona nipinle naa.

Ko sai tun soo di mimo pe, Gomina Ipinle Ekiti, Omowe Kayode Fayemi ti pa’se fun gbogbo awon osise ijoba pata, to wa l’akoso kejila si isale, lati maa sise won latile nitori pe ase ohun siwa sibe.

Ogbeni Omole wa rawo ebe sawon eeyan ipinle nna lati maa tele awon ofin ati ilana t’ijoba lakale lona ati dabobo ara won kuro lowo kiko arun, COVID-19. 

Bee lo si fikun pe, aso ibomu wiwo ati igbese titakete siraeni ti wa pa dandan bayi yika ipinle Ekiti.

Amos Ogunrinde/Elizabeth Idogbe