Ọpọ ilé ìtajà lójú òpópónà alagbaka Àkúrẹ́, nípinlẹ̀ Òndó, ti jẹ́ wíwólulẹ̀ látọwọ́ àwọn òsìsẹ́ ilésẹ́ tó ńrísí àtò gbogbo àti ìdàgbàsókè ìlú ńlá ńlá
Àwọn tóni àwọn ilé ìtàjà ọ̀hún déba tótijẹ́ wíwólulẹ̀ lóru mọ́jú.
Akọròyìn ilésẹ́ wa tó sàbẹ̀wò sí ibi ìsẹ̀lẹ̀ náà jábọ̀ pe, ilé-ìtàjà asọ, ibùdó ìtura àti ibùdó tí wọ́n ti ńfọ ọkọ̀ lágbègbè náà lójẹ́ wíwó lulẹ̀.
Nígbà tó ńsọ̀rọ̀, ọ̀kan lára àwọn tóní ilé ìtàjà Ọlawale Ebimotigha sọpé, ọ̀pọ̀ ọjà òhun lótijẹ́ kíkólọ lẹ́yìn táwọn òsìsẹ́ ìjọba wólulẹ̀.
Elòmíràn tóníilé ìtàjà, ọ̀gbẹ́ni Akin Oriku, ẹnitó sàfihàn ilé táwọn ilésẹ́ ìjọba náà fúnwọn láti kúrò lágbègbè náà lọ́jọ́ kejìlá osù kẹsan, sópé àwọn sisẹ́ tọ́ọ̀ ọjọ́ náà níì.
Nígbà tó ńfèsì alákoso fún ilésẹ́ àtò àbò àti ìdàgbàsókè ìlú ńláńlá, Àlhájì Rasheed Badmus sọpé kó tàpá sófin láti wo àwọn ilé-ìtàjà kan lulẹ̀ lágbègbè ọ̀hún. Kẹmi Ogunkọla/Ladele