Ilé ìwòsàn ọba Adejuyigbe tó wà nilu Ado Èkìtì ni wọn ti yà sọto láti máa ṣètọ́jú àwọn tó bá lugbadi àìsàn ibà ọrẹrẹ ńipinle Èkìtì.

Alamojuto foro ìlera, Dókítà Mojisola Yaya-Kolade ẹnití ó kéde ọ̀rọ̀ yi nilu Ado Èkìtì ni kò tíì sí ẹnìkan tí àìsàn yí wa lara rẹ ńipinle náà.

Ó tẹnumo wípé ìjọba ìpínlè Èkìtì kan gbaradi sílè ni. 

Nígbàtí ó ń sọ̀rọ̀ lórí ìgbaradì wọn fún ibà ọrẹrẹ yí, Dókítà Yaya – Kolade ní gbogbo ẹ̀ka ètò ìlera ńipinle náà ni wọ́n ti ta lolobo tí wọ́n sì ti gbaradì fún àìsàn ibà ọrẹrẹ yí.

Gẹ́gẹ́bí Alamojuto náà ṣe sọ, àwọn ibùdó ìtọ́jú aláìsàn bíi ilé ìwòsàn fún àkànṣe ìtọ́jú Ààrẹ, ilé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣe isègùn tilè ẹ̀kọ́ gíga ìpínlè Èkìtì, ní Ado Èkìtì àti ilé ìwòsàn Federal medical center to WA ni Ido Èkìtì ni wọn ti wà ní ṣepé.

Dókítà Yaya-Kolade ro àwọn ènìyàn láti máa fo owó wọn loorekoore, kí wọ́n máa bo àwọn oúnjẹ wọn ní paapajulo gàárì kí wọ́n sì yàgò fún jíjó igbó.

Ogunribde/Dada Yemisi

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *