Yoruba

Ijọba àpapọ̀ ti sàwárí òsìsẹ́ tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan àtàbọ́, tójẹ́ pé ìwé ìgbanisísẹ́ ayédèrú ni wọ́n lò láti darapọ̀ mọ́ isẹ́ ìjọba.

Olórí òsìsẹ́ nílẹ̀ yí, ọ̀mọ̀wé Fọlasade Yẹmi-Ẹsan ló sọ̀rọ̀ yí di mímọ̀ nílu Abuja.

Ọmọwe Yẹmi-Ẹsan sọpé ó lé ní ẹgbẹ̀rún kan àwọn èyàn tí wọ́n sàwárí ní ẹ̀ka ilésẹ́ kan, tí wọ́n sì rí ẹdẹ́gbẹta òsìsẹ́ ayédèrú láwọn ẹ̀ka min, lásìkò tí wọ́n ńse àyẹ̀wò.

Olórí òsìsẹ́ nílẹ̀ yí tọ́kasi pé, àwọn òsìsẹ́ tọrọ̀ náà kàn ni wọ́n yio yọ kúrò nínú ìlànà àtẹ ìsanwó olósoosù òsìsẹ́.

Folakemi Wojuade

Yoruba

Ìjọba àpapọ̀ ti pè fún àmójútó tó péye láàrin àwọn tọ́rọ̀ kàn nídi àti fòpin sí lílo ọmọdé nílòkulò nílẹ̀ Nàijírìa.

Akọ̀wé àgbà iléesẹ́ ìjọba àpapọ̀ tó wà fún ọ̀rọ̀ òsìsẹ́ àti ìgbanisísẹ́, Dókítà Yerima Peter-Tarfa ló pèpè yí nílu Abuja lásìkò ètò ìdánilẹ́kọ tó wáyé fáwọn olùdarí ẹkùn àti alámojútó láwọn ìpínlẹ̀ nípa ètò àtúntò ìlànà nípa àti fòpin sí lílo ọmọdé nílòkulò lórílẹ̀èdè Nàijírìa àti àwọn aláàlẹ fọ́dún 2021 sí ọdún 2025.

Ọmọwe Tarfa sọ́ọ̀ di mímọ̀ pé ètò ìdánilẹ́kọ náà ló wà fún àgbéga ìmọ̀ àwọn olùkópa fún ilànà náà lórí àti fòpin sí lílo àwọn ọmọdé nílòkulò.

Ó wá rọ àwọn olùkópa pé kí wọ́n se àmúsẹ ìlànà náà, pẹ̀lú kíkópa tó jọjú nínú ìgbésẹ̀ àti fòpin sí lílo ọmọdé nílòkulò.

Babatunde Salaudeen  

News Yoruba

Ijoba apapo ti so di mimo pe yoo to osu mejidinlogun sasikoyi kohun to le yoo owo iranwo epo robi.

Alakoso keji foro epo bentiro, Ogbeni Timpre Silva lo soro naa nilu Abuja lasiko to n baa won akoroyin ile ijoba fowowewo loti oro naa.

Alakoso ohun salaye pe oro lori yiyo owo iranwo epo robi lowa ninu iwe ofin to room eepo bentiro, pelu alaye pe akosile afinkun ojo naa awon yoo fi sowo sile igbimo asofin ileyi fun atunse lojuna ati dekun iwa ti ko tele ofin lojo iwaju.

Ogbeni Sylva salaye siwaju pe Aare Muhammadu Buhari lo ti gba lori afikun ojo naa nitori nkan to seese kirufe igbese bee ni lara oro okoowo.

Alakoso naa salaye pe afikun ojo ohun yoo le fun awon eni-oro-kan laaye ati ri daju pee to ipese iderun w anile saaju igbawole oro yiyo owo iranwo naa.

Okareh/Olaopa

Yoruba
 

Ijoba apapo ti soo di mimo wi pe won yoo se idasile ebu ifopo esekuku meta otooto si okookan ati ipinle to n pese epo robi lagbegbe Niger/Delta.

Alakoso keji foro ayika nile yi, Oloyo Sharon Keazor lo sipaya oro yi ninu atejade to fi sita nilu Abuja.

O salaye wipe, awon ebu ifopo meta yi yoomu ona abayo wa fawon onise owo to n fi ise ebu ifopo se ise oojo, ti yoo si tun fun won lanfaani ati jawo ninu fifo epo robi lona ti ko bofin mu.

Alakose naa tenumo pea won ebu ifopo alabode yi ni won yio ti maa se amulo ohun elo ti won pese labele pelu awon ileese ijoba to je akosemose bii ileese ijoba apapo to wa fun ohun alumoni epo robi, ile sko giga fasiti ijoba apapo to wa fun epo petirolu, eyi to wa nilu effurun ati ile eko giga fasiti Ahmadu Bello to wa nilu Zaria.

Gege bo se wi, ijoba apapo yoo tun seto idanileko fawon onise owo ti yoo maa fo epo naa nipa amojuto ayika, lona tise won yoo fi pegede.

Babatunde Salaudeen

Yoruba

Ijoba apapo ti so pe ko si ooto ninu iroyin to n ja rohinrohin pe aarun romolapa romolese ti be sile lawon ipinle kookan.

Ijoba fowo idaniloju re soya pe ko ti si isele aarun naa tuntun nile yi lati odun 2016.

Ogaagba eto idagbasoke ilera alabode, Dokita Faisal Shuaib eni to ni ko si ooto pea run na tun ti seriyo, sope ni loolo yi ile yi ni, awon to ni, to fe to irinwo niye yika ipinle meta din logbon ati oluulu ile yi Abuja.

Dokital Shuaib wa fi da awon eeyan ile yi loju pe, won yoo tesiwaju lati ma lo yika ile yi, ti ipolongo yo si tesiwaju pelu awon torokan lati le dekun kiko arun wole lati orileede okeere.

O wa tenumo Pataki, ki awon obu atalagbato ma setoju awon omo won dunju, lai yo gbigba abere ajesara sile, eyito n dena awon arun.

Ololade Afonja

Yoruba

Ìgbìmọ̀ amúsẹ́yá ìjọba àpapọ̀ fárùn covid-19 rọ àwọn èèyàn ilẹ̀ yíì láti sọdún kérésìmesì àti ìsinmi ọdún titun bótiyẹ.

Alága ìgbìmọ̀ náà títún se akọ̀wé ìjọba àpapọ̀ ọ̀gbẹ́ni Boss Mustapha ló sọ̀rọ̀ yíì nínú àtàjáde nílu Abuja.

Ọgbẹni Mustapha níì ó se pàtàkì, káwọn èèyàn mú ìgbésẹ̀ àbò wọn àti pípa àwọn ìlànà atẹle fárùn covid 19 mọ̀, láti fòpinsí ìtànkálẹ̀ àrùn covid 19, pẹ̀lú bí orílẹ̀dè yíì se ńkojú ìkẹ́rin àrùn náà.

Bakana lótún rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sáwọn èèyàn ilẹ̀ yíì, láti yàgò fún àpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ èrò.

Ọgbẹni Mustapha wá ni osese kí àjọ psc gbé ìgbásẹ̀ fífòpinsí àwọn àpéjọ kan, isede láwọn apá ipikan tí àkọsílẹ̀ àrùn náà bá tún búrẹ́kẹ́ síì.

Elizabeth Idogbe

Yoruba

Ìgbìmọ̀ alásẹ ìjọba àpapọ̀ ti buwọlu isẹ́ àkànse mẹ́rìndílógún lójúnà àti mú àgbéga báà iná mọ̀nà-mọ́ná nílẹ̀ yíì.

Alákoso fóun àmúsagbára, Àlhájì Abubakar Aliyu sọ̀rọ̀ yíì fáwọn oníròyìn lẹ́yìn ìpàdé ìgbìmọ̀ alásẹ èyítí igbákejì ààrẹ ilẹ̀ yíì ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmi Osinbajo darí rẹ̀ nílu Abuja.

Ó níì ìpèníjà kan gbogi tó ńkojú ìdúró ree iná mọ̀nàmọ́ná nílẹ̀ yíì ní kíkùnà nídi pínpín iná mọ̀nàmọ́ná tówànílẹ̀ lọ́nà tóyẹ.

Alákoso ọ̀ún tọ́kasi pé, ibùdó apako pin soso lówà nílẹ̀ yíì níbití wọ́n ti kaseyọri le ba ẹ̀ka wọn.

Elizabeth Idogbe

News Yoruba

Ijoba apapo ti di ebi afefe gaasi idana to fojoojumo gbowo lori ru bi eroja naa ti won  n pese se kere, ati bi o se di imi eegun lawujo agbaye.

Oludari agba fun ileese elepo robi nile yi, NNPC, Mele Kyari to soro nilu abuja tenumo pe ijoba ti n gbiyanju lori ati rii daju pe agbega ba ipese afefe gaasi faraalu.

Ogbeni Kyari salaye wi pe, eroja naa to gbowo lori ko seyin iye ti won n taa kaakiri oja lagbaye.

O tun pe fun atileyin ijoba latodo awon oludokowo aladani lona ati fi le mu iderun ba iye taraalu yoo maa ra afefe gaasi.

Net / Salaudeen

Yoruba

Igbakeji aare , ojogbon Yemi Osinbajo ti fi ireti han  wipe  orile ede Naijiria losi wa loju ona toto lori didari oro aje gba ibomiran nipa tenpele mo awon oja ti won nko lo ile okeere ti ko ni nknakan se pelu epo robi eyiyi ajo tonrisi oro kiko oja lo ile okeere nile yi NEPC sagbateru re.Ojoogbon Osinbajo soro yi nigbati o gbaalejo iko kan lati inu ajo NEPC eyiyi oga agba ajo naa to nfipo sile, Ogbeni Segub Awolowo ko sodi.O wa pe awon torokan leka naa lati jigir si awon ipenija to nbo lona nitori awon odun tonbo ni yio dan ile yi wo lori ipinnu re lati dari oro aje gba ibomiran.Ninu oro re, Ogbeni Segun Awolow slaye bi nkan to se nlo lori eto fife  kiko oja lo ile  okeere loju, eyiyi o nio se pataki fun didari oro aje ile yi gba ibomiran ti ijoba apapo to wa tenumo pelu awon elo ajo naa, ile yi lo wa loju ona ati mu  idagbasoke ba eka ti kiise loju ona ati mu idagbasoke ba eka  ti kiise tepo robi ko sai ro awon torokan lati mase kaare ninu akitiyan won .

Ayodele Olaopa

Yoruba

Àarẹ Muhamadu Buhari ti fẹ̀mí ìmoore hàn sí àwọn alásẹ ilẹ̀ Amẹrica lórí bí wọ́n se gba ilẹ̀ Nàijírìa láàye láti ra ohun ìjagun fún gbígbógun ti ìgbésùmọ̀mí tó fimọ́ ètò ìdánilẹ̀kọ tíwọ́n se fáwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Nàijírìa.

Àarẹ Buhari sọ̀rọ̀ náà nílu Abuja lásìkò tón gbàléjò akọ̀wé ìjọba ilẹ̀ Amẹrica, ọ̀gbẹ́ni Anthony Blinker.

Àarẹ sàlàyé pé, ìrànwọ́ tílẹ̀ yí tín rí gbà ti jẹ́ kin ǹkan padàbọ̀ sípò lẹ́kùn ìlà orun àríwá àarẹ tún sàlàyé pé ilẹ̀ Nàijírìa àtàwọn alámulegbe rẹ̀ ni wọ́n tín gbé pẹ̀lú ipa ti ko da tó ti àyípadà ijú ọjọ́ fa, eléyi tó fa bí alagbalugbu omi Lake Chad se kun ju bó se wà tẹ́lẹ̀ lọ tó sin ni ipa ti kó da lara miliọnu lanà ọgbọ̀n èyàn làwọn orílẹ̀èdè lẹ́kùn Lake Chad.

Àarẹ sàlàyé pé ọ̀rọ̀ náà lón fa bí ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ se ń sá kúrò lẹ́kùn náà ló sókè òkun.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ni ọ̀gbẹ́ni Blinker ti wá sọpé ilẹ̀ Amẹrica àti ilẹ̀ Nàijírìa lóní ìpèníjà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí àisètò àbò pẹ̀lú síse ìlérí lórí wíwá ojútu sáwọn ìpèníjà náà.

Ayodele Ọlaọpa

News Yoruba

Ijoba apapo ti kesi agbasese to n se ise akanse ina-oba ni Zungeru, Nipinle Niger lati ridaju pe ise akanse naa pari  o petan osu kejila odun yi.

Alakoso foun amusagbara, Ogbeni Abubakar Aliyu so eyi nilu Anuja, lasiko to ngba agbasese to nsise ohun lalejo lofiisi re.

Alakoso wa salaye pe ipenija ti agbasese naa n koju yoo je wiwa ojutu si.

Nigba to un fii idunu re han lori abo agbases ohun, Ogbeni Aliyu seleri pe, kosi ohun Kankan ti yoo dii asepari ise naa lowo.

Net/Idogbe

Yoruba

Ijoba apapo ti sope ohun ti se ifilole okan-o-jokan eto lawon ekun idibo mefeefa to n be nile yi ki amuse le deba adehun pipose ina oba fun milionu marun idile pelu itansan oorun titi odun 2023.

Igbakeji Aare ileyi, Ojogbon Yemi Osinbajo lo soro naa lasiko to n siso loju ipade apero lori oun amusagbara nilu Abuja. Ojogbon Osinbajo ti alakoso keji foro ayika, Arabinrin Sharon Ikeazor soju fun, salaye pe igbiyanju naa lo wa ni ibamu pelu eto toro mo oun amusagbara.

O sope eto ohun ni yoo lapa lara apapo milionu meedogbon omo ileyi pelu pipese ise fun egberun lona otalerugba odin mewa eyan.

Ewe, eni tiise oga agba ile ise elepo robi nileyi, Malam Mele Kyari sope ile ise naa ni yoo ma ate siwaju lori atunse eka ohun amusagbara ile yi.

Ayodele Olaopa

News Yoruba

Ijoba apapo ti kede liana erongba re lati maa gbe abere ajesare arun covid-19 lo sawon ile ijosin omoleyin Kristi atawon aaye ijosin mi lara liana to ti pare fun gbigba abere ajesera naa.

Oga agba ajo eleto ilera alabode nileyi Dokita Faisal Shuiiab lo yoju erongba naa sita nilu Abuja.

Ijoba apapo ti bere eto pinpin awon ohun eelo iko ounje pamosi fawon agbe lawon ipinle mokandinlogun nile yi lojuna ati ri daju pe aabo wa fun ounje fogunlogo omo ile Nigeria.

Eto pinpin ohun elo naa fawon agbe lowa ni ibamu pelu akosile iroyin lori aisi nkan iko ounje pamosi fun ogunlogo agbe to sin fa airogbo eto oro aje laarin awon agbe torokan.

Akowe agba nile ise eto ogbin ati idagbasoke igberiko, Dokita Ernest Umakhihe lo side eto pinpin ohun elo naa fawon agbe, awon obinrin to ku die kaato fun atawon odo nilu Ilorin tiise olu ilu Ipinle Kwara.

Dokita Umokhihe famin idaniloju han pe eto naa yoo se igbelaruge ipese ounje ohun ipese inkan ti yoo si jeki oro aje ohun awujo dagba soke si.

O salaye pe ijoba ti safihan liana amojuto kiko ere oko tiko munadoko lasrin awon agbe gegebi ipenija kan gbogi to n koju idagbasoke ise agbe nile yi.

  Alamu/Olaopa

News Yoruba

Ijoba apapo ti kede liana erongba re lati maa gbe abere ajesare arun covid-19 lo sawon ile ijosin omoleyin Kristi atawon aaye ijosin mi lara liana to ti pare fun gbigba abere ajesera naa.

Oga agba ajo eleto ilera alabode nileyi Dokita Faisal Shuiiab lo yoju erongba naa sita nilu Abuja.

O salaye pe, ni ibamu pelu sise ise po pelu awon ipinle, ijoba apapo ti sagbekale ilana gbigba abere naa fawon osise lawon ile ise ijoba, leka jeka. Lajo lajo awon ile ise aladani atawon ile ise nla-nla to fi mo awon ise  ijosin, awon molebi won atawon alabagbe to fimo awon osise feyinti.

Dokita shuaib salaye pea won yoo si maa tesiwaju lati maa mojuto ipa ti abere naa n imago ara awon eyan, pelu iroyin to nise pelu bi abere naa se n ri logo ara.

O wa tun fi ami idaniloju re han lori ifokansin ijoba apapo nipase ile ise eto ilera ijoba apapo fun agbekale abere ajesara ti aabo wa fun, to sise to si je ofe ki arun covid-19 le di afiseyin teegun alaro fiiso.

Alamu/Olaopa

News Yoruba

Ìjọba àpapọ̀ ti setán láti gba owó tó wọ ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ milliọnu naira tí wọ́n sesi san fun àwọn Dókítà onímọ̀ ìsègùn tó lé ní ẹdẹgbẹta níye yíká orílẹ̀ èdè yí.

Alákoso fọ́rọ̀ isẹ́ àti ìgbanisísẹ́ Sẹnatọ Chris Ngige ló sọ̀rọ̀ yí di mímọ́ lásìkò tón dáhun ìbere látọ̀dọ̀ àwọn akọ̀ròyìn nílu Abuja.

Alákoso se lálàyé pé, àwọn Dókítà tọ́rọkàn ni wan fún lówó tí kò si wọn, látinú owó tó wà fún ìdánilẹ́kọ fáwọn onímọ̀ ìsègùn tón gbélé kàwé láti di akọ́sẹ́mọsẹ́.

Ó ní àwọn dókítà tí wọ́n fún lówó tí kò tọ fún wọn yi, ni wọ́n sàwárí orúkọ wọn, nínú orúkọ tó jk ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ, níye tí dókítà àgbà fún ilí-ìwé ẹ̀kọ́ni tìjọba àpapọ̀ gbé kalẹ̀.

Sẹnatọ Ngige, sọ̀rọ̀ yan kankan pé, owó tótó owó ni wọ́n ti rí gbà padà látọ̀dọ̀ àwọn dókítà tọ́rọ̀kan tí ìgbésẹ̀ sin lọ láti gba ìyókù padà.

Lórí ọ̀rọ̀ ìyansẹ́lódì táwọn dókìtà tón gbé inú ọgbà láti di akọ́sẹ́mọsẹ́ gùnlé, alákoso láti dákẹ́ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan wọ́n, tí wọ́n bá ti gbà láti padà sẹ́nu isẹ́.

Ó wá tẹnumọ pé ìlànà, ẹniti ko sisẹ́ kòní gba owó osù, ni ìjọba yo sàmúlò nítorípé ìgbésẹ̀ yi ni wọ́n lo ni gbogbo àgbàyé gẹ́gẹ́bótiwà nínú òfin kẹta le logoji tó wà fún bí àwọn bá wa lárin òsìsẹ́ àti ìjọba.

Banjọ/Afọnja

News Yoruba

Ijoba apapo ti fokan awon osise papako ofurufu ile yi bale lori aheso pe boya won yo da awon kan duro lenu ise nipa igbese tijoba fe gbe lori ati yonda awon oju opo oko ofurufu merin Pataki fawon ti yoo soo di otun.

Alakoso eto irinna ofurufu nile yi Hadi Sirika lo fowo ero yi soya lasiko ipade ori ero ayelujara pelu awon toro kan leka eto iirina ofurufu nilu Eko nipa ini ti inkan de duro lori igbese tijoba fe gbe nipa awon papako ofurufu mereerin ti oro kan.

Ogbeni Sirika salaye wi pe, leyi ti joba yoo ba fid a awon osise kan duro, se ni won yoo tun gba osise sii, nipa bo se je, pe opo papako ofurufuloje pe osise ti won ni ko to won

Alakoso naa tenumo pe ijoba o setan lati ohun amusoro eyi lo je ki won fe yonda re fun awon ti yio soo di ti igbalode, lona ti yio tun fi le maa pawo sapo ile yi ju tateyinwa lo.

Awon papako ofurufu merin tijoba fe yonda ni papako ofurufu Mallam Aminu Kano, Papako Ofurufu Murtala Muhammed, Papako Ofurufu to wa nilu Port-Harcourt, ati Papako Ofurufu Nnamidi Azkwe.

Babatunde Salaudeen

Yoruba

Pẹ̀lú bí ìgbésẹ̀ láti mú àyípadà dé bá ńkan ọ̀sìn nílẹ̀ yí, ìjọba àpapọ̀ ti ní kí ibùdó tí wọ́n yo ti ma kẹ́ran jẹ̀, tí wọ́n yà sọ́tọ̀, kó gbérasọ, nípinlẹ̀ mọ́kàndínlógún láriwá ilẹ̀ yí, tófimọ́ ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ àti Ògùn lẹ́kùn ìwọ̀ orun gúsù ilẹ̀ yí.

Nígbà tón sọ̀rọ̀ nílu Abuja, lásìkò ìpàdé ẹlekẹrin lé lógójì, àjọ tón rísí ẹ̀ka ọ̀gbìn, àti ìdàgbàsókè ìgbèríko, alákoso fọ́rọ̀ ọ̀gbìn àti ìdàgbàsókò ẹsẹ̀kuku, ọ̀gbẹ́ni Sambo Nanono, jk kó di mímọ̀ pé ìpínlẹ̀ méjìlélógún àti olúlu ilẹ̀ yí ló ti forúkọ sílẹ̀ fún ètò ọ̀hún.

Ó ní ẹ̀ka kan ni Dutch ti ní àjọsepọ̀ pẹ̀lú ìjọba láti bẹ̀rẹ̀ ìsí àkọ́kọ́ isẹ́ àkànse ọ̀hún nípinlẹ̀ Nasarawa.

Alákoso Nanono, tẹnumọ́ pé, tí wọ́n bá parí gbogbo isẹ́ ohun, yo fòpin sí ìjà lárin àwọn àgbẹ̀ àti darandaran.

Bákanà ni yo jẹ ànjàní láti mọ dunjun sisin ẹran nílànà ìgbàlódé fún àwọn tón kó ẹran jẹ̀.

Ó sọ síwájú pé yo fàyègba àyíká tó rọrùn fáwọn olùdókowò láti dókowò lẹ́ka ọ̀hún.

Olukayọde Banjọ

News Yoruba

Ijoba Apapo feki awon toro kan gbogbo ati awon lajolajo lati maa da awon eniyan leko ise owo lona ati gbogunti airi ise se ati ise oun osi.

Alakoso keji foro ile ise nla-nla, okoowo ati idokowo nile yi, Arabinrin Mariam Katagum eniti o pe ipe yi nibi ipade apero kan nilu Abuja so wipe ise oun osi ati airisese wa lara ipenija tile yi nkoju to si ti sokunfa oniruru iwa ti ko bojumu lawujo.

O wa salaye wipe ise tabua ni riro awon odo lagbara ti ko ye ki won da ajo to nrisi idanileko awon odo nile ise nla-nla ITF ati awon lajolajo ijoba nikan.

Arabinrin Katagum wa ni ijoba apapo ti nsamulo awon liana kan lojunna ati mu ayipada ba oro yi.

Gegebi o se so, igbese yio mu ki ile yi ja lenu emu didarade epo robi nikan nipase didari oro aje gba ona miran.

 Net/Dada

Yoruba

Ijoba apapo ti siso loju ipinnu re lati se atileyin lori awon nkan elo lori eto aabo, eyi to fe gunle lati ri daju pe alaria ati idagbasoke de ba agbegbe Niger Delta.

Alakoso to n ri si oro Niger Delta Senator Godswill Akpabio, lo soro yi lasiko to n gba akowe agba fun igbimo fidie fun egbe oselu APC, Senator Akpan Udohedehen lofisi re nilu Abuja.

Alakoso tokasi pe, eto tin lo lowo lati se idasile eka Pataki nileese olopa fun agbegbe ohun.

Ninu oro Akowe, fun igbimo fidie ti APC, Senator Akpan Udbohedehen salaye pe Pataki abewo naa ni ati mo riri ki won si da abewo pada fun alakose Senator Godswill Akpabio ni ofisi egbe oselu naa.

Sherifdeen/Wojuade 

Yoruba

Alakoso foro iroyin ati asaa, Alhaji Lai Mohammed ni ilana ise iroyin tode oni nipase ero ayelujara, DSO, yoo ye fifilole lawon ipinle metala otooto kotodi opin odun yii.

Alakoso soro yii nipinle eko nibi ifilole ilana ohun pelu alaye pe eto naa yoo yaa kanakan jake-jado ile yii,

Alhaji Mohammed sope ifilole tipinle Eko, samii ibere ipin keji ilana naa, eyi ti iiwo ti waaye lori re lati odun meta seyin leyin ifilole re lawon ipinle merin ototo Plateau, Kwara, Kaduna, Enugu ati olu ilu ile yii Abuja.

Oni bi o tile jepe, o gba iko ero mohunmaworan igbalode lodun meta lati gunle sipinle eko, lati ibiti won pari ise si, tise ipinle osun, amo nibayi oni won ti setan fun ise kiakia.

Alakoso Mohammed wa fikun pe laifi ti ipenija yoowu se, ilana  ise iroyin lode oni nipase ero ayelujara yoo pari nibamu pelu akoko tiwon filede tise ojo keje  osu kejila odun 2022.

Idogbe

News Yoruba

Ijoba apapo orileede yi ti sekilo fawon omo orileede yi, lati yago kuro nidi gigunle awon irinajo lo sawon ilu ti ibesile kokoro aarun covid-19 n bafinra fun igba keta, papa  julo ile India nibi to ti gbile jula.

Bakanna, lo tun menuba ile South Africa, Turkey ato rileede Braizil ninu oro igbanniyanju lori oro irin ajo.

Alabojuto agba fun igbimo amuseya ile-ise aare tiwon gbekale foro covid-19, omoowe Mukhtar Muhammad lo siso loju oro yii nibi ipade awon oniroyin to waye nily Abuja. 

Bee lo tun sekilo fawon omo orileede yi kan tiwon fo dengbere mawon ofin atilana to dena itankanle arun covid-, kiwon sora se nitori pe, arun naa ko tii kase nile tan.

Omowe Muhammad wa tokasi pe, ofin titakete lawujo opo ero, atiwiwo ibomu, siwa digbi, lawon ojutaye bi oja, ibudo igbafe awon ile itaja igbalode to fi mawon ibomiin lati itankanle kokoro arun covid-19 patapata.

Net/Wojuade

News Yoruba

Ijoba apapo ti sope didokowo leka nkan osun nile Naijiria lo le mu ki owo toto million lona metalelogbon ko kun agbega eto oro aje nile yi.

Alakoso feka eto ogbin at idagbasoke igberiko Sabo Nanono lo je koro yi di mimo fawon akoroyin nilu Abuja, pelu atokasi pe ijoba apapo hin sise kara lati le gbaruku tie ka yi fun agbega eto oro aje.

Oni erongba ijoba apapo lati pin eto oro aje si yeleyele, kuro nidi epo roobi nikan soso, yo bere sinu soo.

Ogbeni Nanono sope, lati wa mu keto naa yori sir ere, ilese naa ti bere sini samulo awon ona igbalode tie ka eto ogbin yo fi tunbo rugogo si.

Banjo/Afonja

Yoruba

Ijoba apapo ti sodi mimo pe oohun ko ni se iduna-dura botiwu omo pelu iko agbehon, janduku tabi agbesumomi, nidi iwoyaja re pelu eto aabo ipenija to nkoju nile yii.

Olubadamoran feto abo lorileede yii, Ogagun Babagana Monguna lo soro yi nilu Abuja.

O salaye awon ipinu ijoba lokan ojokan llati satileyin fun iko alaba lati mu iwa odaran to ti gba awon apa ibikan nile yii kan dii ohun afiseyin teegun nfiso.

O tokasi pe, ijoba yoo gbe gbogbo igbese tooye tofimo fifi awon omo-ogun tooye sowo nidi fifopin iwa igbesunmomi nile yii.

Ogagun Manguna fikun pe ijoba yoo koni faaye-gba inabilorukoje tabi kawon odaran fi koolu awon alaise.

Idogbe

Yoruba

Awon obinrin nigberiko, to fimo awon to fara kasha ninu rogbodiyan oja Shasha to waye laipe yi ni won yo gba nkan iranwo lati inu eto wyi ti Aare Muhammadu Buhari gbe kale lati mu ki agbega de ba okoowo ati eto igbayegbadun.

Eto naa ti won bere ni gbongan Western to wa ni Secretariat Ibadan, ni opolopo awon eeyan pejopo si, ninu eyi ti awon to ni ipenija ara to fimo awon ti to rowo hori lati awon igberiko peju pese si.

Ninu oro alakoso, foro to mojuto omoniyan, didoola isele pajawiri to fimo idagbasoke igberiko, Hajia Sadia Farouk so pe o le ni eeyan egberun marun tie to ohun fojusun nipinle Oyo, a mo ti awon eeyan to le ni egberun lona adajo ni won yo janfani eto naa, lapapo.

 Alakoso to kasi pe owo to few o billionu kan naira ni won ti pin fawon eeyan nipinle Oyo labe Ileese to n risi igbaga idokowo ati igba yegbadun eto ti Aare Muhammadu Buhari.

Nitire, alakoso foro obinrin ati idagbasoke awujo, Alhaja Faosat Sanni, so pe Gomina Ipinle Oyo onimo ero Seyi Makinde yo ma se atileyin fun gbogbo eto eyi ti won lakale lati gbe awon eeyan kuro ninu ise on osi.

Famakin/Afonja 

Yoruba

Agbejoro agba Ogbeni Dayo Apapta sope laipe yi ni ijoba apapo yo se ifilole iforuko sile lori ero ayelujara lori dukia ti won ti gba pada.

Ogbeni Apata so pe igbimo to nrisi isakoso lori awon dukia ijoba ti won gba pada ni yo sise naa.

Lasiko ti agbejoro agba lo se abewo si oluileese ajo ton gbogunti sise owo ilu kumo-kumo ati eto oro aje nilu Abuja ni o ti siso loju oro yi.

Ogbeni Apata ti se Alaga igbimo naa, soro idaniloju pe ijoba apapo yo ri awon dukia yi lo pada lona ti yose ara ilu lanfani.

Afonja