Yoruba

Ìjọba àpapọ̀ pè fún ìgbésẹ̀ fifòpin sí lílo ọmọdé nílòkulò

Ìjọba àpapọ̀ ti pè fún àmójútó tó péye láàrin àwọn tọ́rọ̀ kàn nídi àti fòpin sí lílo ọmọdé nílòkulò nílẹ̀ Nàijírìa.

Akọ̀wé àgbà iléesẹ́ ìjọba àpapọ̀ tó wà fún ọ̀rọ̀ òsìsẹ́ àti ìgbanisísẹ́, Dókítà Yerima Peter-Tarfa ló pèpè yí nílu Abuja lásìkò ètò ìdánilẹ́kọ tó wáyé fáwọn olùdarí ẹkùn àti alámojútó láwọn ìpínlẹ̀ nípa ètò àtúntò ìlànà nípa àti fòpin sí lílo ọmọdé nílòkulò lórílẹ̀èdè Nàijírìa àti àwọn aláàlẹ fọ́dún 2021 sí ọdún 2025.

Ọmọwe Tarfa sọ́ọ̀ di mímọ̀ pé ètò ìdánilẹ́kọ náà ló wà fún àgbéga ìmọ̀ àwọn olùkópa fún ilànà náà lórí àti fòpin sí lílo àwọn ọmọdé nílòkulò.

Ó wá rọ àwọn olùkópa pé kí wọ́n se àmúsẹ ìlànà náà, pẹ̀lú kíkópa tó jọjú nínú ìgbésẹ̀ àti fòpin sí lílo ọmọdé nílòkulò.

Babatunde Salaudeen  

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *