Ìjọba àpapọ̀ ti setán láti gba owó tó wọ ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ milliọnu naira tí wọ́n sesi san fun àwọn Dókítà onímọ̀ ìsègùn tó lé ní ẹdẹgbẹta níye yíká orílẹ̀ èdè yí.

Alákoso fọ́rọ̀ isẹ́ àti ìgbanisísẹ́ Sẹnatọ Chris Ngige ló sọ̀rọ̀ yí di mímọ́ lásìkò tón dáhun ìbere látọ̀dọ̀ àwọn akọ̀ròyìn nílu Abuja.

Alákoso se lálàyé pé, àwọn Dókítà tọ́rọkàn ni wan fún lówó tí kò si wọn, látinú owó tó wà fún ìdánilẹ́kọ fáwọn onímọ̀ ìsègùn tón gbélé kàwé láti di akọ́sẹ́mọsẹ́.

Ó ní àwọn dókítà tí wọ́n fún lówó tí kò tọ fún wọn yi, ni wọ́n sàwárí orúkọ wọn, nínú orúkọ tó jk ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ, níye tí dókítà àgbà fún ilí-ìwé ẹ̀kọ́ni tìjọba àpapọ̀ gbé kalẹ̀.

Sẹnatọ Ngige, sọ̀rọ̀ yan kankan pé, owó tótó owó ni wọ́n ti rí gbà padà látọ̀dọ̀ àwọn dókítà tọ́rọ̀kan tí ìgbésẹ̀ sin lọ láti gba ìyókù padà.

Lórí ọ̀rọ̀ ìyansẹ́lódì táwọn dókìtà tón gbé inú ọgbà láti di akọ́sẹ́mọsẹ́ gùnlé, alákoso láti dákẹ́ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan wọ́n, tí wọ́n bá ti gbà láti padà sẹ́nu isẹ́.

Ó wá tẹnumọ pé ìlànà, ẹniti ko sisẹ́ kòní gba owó osù, ni ìjọba yo sàmúlò nítorípé ìgbésẹ̀ yi ni wọ́n lo ni gbogbo àgbàyé gẹ́gẹ́bótiwà nínú òfin kẹta le logoji tó wà fún bí àwọn bá wa lárin òsìsẹ́ àti ìjọba.

Banjọ/Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *