Yoruba

Alákoso iléesẹ́ ọlọ́pa ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, ọ̀gbẹ́ni Nwachukwu Enwonwu ti sèkìlọ̀ fáwọn aráàlu pé kí wọ́n yàgò fún lílo òfin lọ́wọ́ ará wọn, léyi tó dàpè ní ìdájọ́ láàye ara ẹni.

Alákoso sípaya ọ̀rọ̀ yí nílu ìbàdàn pẹ̀lú àlàyé wí pé, káwọn èèyàn tètè máà fi ọ̀rọ̀ tó iléésẹ́ ọlọ́pa tó bá wà nítòsí létí nígbà yóòwù tí wọn bá mú ọ̀daràn, yàtọ̀ fún síse lelajọ láàye ara wọn, léyi tó jẹ́ pé wọ́n léè fìyà jẹ aláisẹ.

Ọgbẹni Enwonwu tún sèkìlọ̀ lórí yinyin ìbọn ọdún bíì banger àti àwọn ǹnkan a bú gbàmù min fún pọ̀pọ̀sìnsìn ọdún.

Bákana náà ló tún korò ojú sí síse àpéjọpọ̀ òpópónà lásìkò àti lẹ́yìn ọdún.

Fọlakẹmi Wojuade

Yoruba

Alákoso ilésẹ́ ọlọ́pa nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, ọ̀gbẹ́ni Nwachukwu Enwonwu ti sèkìlọ̀ fáwọn ọlọ́kadà, àwọn òntàjà àtàwọn onísẹ́ọwọ́ lọ́jà Agodi Gate láti dẹ̀hìn nídi bába àwọn ǹkan ìníì ìjọba jẹ́ àtàwọn ilésẹ́ ọlọ́pa.

Nínú àtẹ̀jáde tálukoro ilésẹ́ ọlọ́pa nípinlẹ̀ ọ̀yọ́, ọ̀gbẹ́ni Gbenga Fadeyi fisíta tọ́kasi pé, ìsẹ̀lẹ̀ dídánásun ilésẹ́ ọlọ́pa lákokò tójẹ́ kíkọ́ ladún 1926, jẹ́ àdánù ńlá.

Ó sàlàyé pé, ilésẹ́ ọlọ́pa ọ̀hún léèdi ibùdó ìtàn fún orúlẹ̀èdè yíì.

Ó tọ́kasi pé, àwọn ọlọ́kadà àtàwọn òntàjà lọ́jà ìsọ̀ àrt Gate ló dasọ asa náà soro.

Ọgagun Enwonwu kò sài wá sèkìlọ̀ pé, ẹniyoowu tọ́wọ́ bátẹ̀ nídi ìwà ibe yóò fimú káta òfin.

Alákoko ọ̀hún wá sèlérí àbò tó gbópọn ní tìlúù-tooro ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ láti ridájú àláfìa jọba sáàjú àti lẹ́yìn pọ̀p.

Abisola Oluremi/Idogbe