News Yoruba

Láti osù tónbọ̀ lọ ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ nípasè ilé isẹ́ ètò ìlera, yóò bẹ̀rẹ̀ sìnípín àwọn àpò apa ẹ̀fọn tó lé ní milliónu márun fáwọn ilé kọ́ọ̀kan tón bẹ yíká gbogbo àwọn ìjọba ìbílẹ̀ nípinlẹ̀ ọ̀yọ́.

Igbákejì olùdarí ẹ̀ka òtò ìlera, aráàlu nílesẹ́ ètò ìlera ọ̀hún, Díkítà Olubunmi Ayinde tó sísọ lójú ọ̀rọ̀ náà nínú ìpàdé àwọn oníròyìn kan tó wáyé nílu ìbàdàn, sàlàyé pé, ìgbésẹ̀ náà ló wà níbamu pẹ̀lú àjọsepọ̀ ilé isẹ́ ètò ìlera ìjọba àpapọ̀ àtìjọba ilẹ̀ America.

Dókítà Ayinde fi kálàyé rẹ̀ pé, ọjọ́ kejìdínlógún bẹ̀ẹ̀rẹ̀ sini pín àpò apa ẹ̀fọn náà, lẹ́yìn táwọn èèyàn bá ti gbawọn iwe pélébé pélébé tíwọ́n yóò fi leto si àpò apa ẹ̀fọn ọ̀hún ni gbigba, èyí tí yóò wáyé láàrin ọgbọnjọ osùkejì sí ọjọ́ keje osù kẹjọ ọdún yíì.

Kò sài fikun pé, mímú ilégbe ẹnikọọ kan ni wọ́n yóò kó àwọn káàdi kékèké náà lọ, tó sì rọ àwọn èèyàn láti ridajú pé wọ́n gbàwọn káàdi ọ̀hún, nítorí pé, tíwọ́n kò bá tiri gbà, wọn kò ní lánfàní láti gba àpò apa ẹ̀fọn náà.

Net/Wojuade     

Yoruba

Ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ti tọwọ́bọ ìwé padéhùn àfẹnukò kan lórí sísanwó osù tuntun fáwọn òsìsẹ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga tó jẹ́ tìpínlẹ̀ yíì.

Ilé isẹ́ ètò ẹ̀kọ́ ìpínlẹ̀ yíì tó wà ládugbò Agodi secretariat ìbàdàn niwọ́n ti tọwọ́ àdéhùn náà.

Níbi ètò náà, lalákoso fétò ẹ̀kọ́, ọ̀gbẹ́ni Ọlasunkanmi Ọlalẹyẹ ti sọ́ọ̀di mímọ̀ pé, àfẹnukò náà ló wà níbamu pẹ̀lú ìlànà ìsanwó osù òsìsẹ́ tíjọba àpapọ̀ gbékalẹ̀.

Nínú ọ̀rọ̀ tiẹ̀, alága àgbáríjọpọ̀ ẹgbẹ́ òsìsẹ́ láwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga tó jẹ́ tìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, ọ̀gbẹ́ni Sẹgun Oyewumi, sọ pé, àdéhùn náà yóò sànfàní fáwọn ọmọ ẹgbẹ́ ọ̀hún, pẹ̀lú àrọwà síjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ pé, kò ní gbogbo àwọn ìlérí rẹ̀ se.

Adebisi/Wojuade

Yoruba

Gómìonà Seyi Makinde tìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, ti se ìfilọ́lẹ̀ ìsí àkọ̀kọ̀, sísètò ìjọba lórí òpó ẹ̀rọ ayélujára pẹ̀lú ẹ̀rọ ayábiasa tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan níye, tí àwọn ilésẹ́ ìjọba àti ẹ̀ka yo ma lo nípinlẹ̀ yí.

Ètò ọ̀hún lówáyé níbùdó ìmọ̀ ẹ̀rọ ayélujára tó wà ní secretariat Agodi ìbàdàn.

Gómìnà Makinde lásìkò tón wo àwọn ẹ̀rọ ayárabíasa tí wọ́n sẹ̀sẹ̀ rà yí, se lálàyé pé, àfojúsùn ìsèjọba òun ni láti gbé ètò ìjọba lé orí ẹ̀rọ ayálujára, kó kúrò ní bí wọ́n tin se látẹ̀yìnwá.

Nígbà tón mú Gómìnà àti ikọ̀ tó kọ́wọrìn pẹ̀lú rẹ̀, yípo àwọn on èlò yí, olùdámọ̀ràn pàtàkì sí Gómìnà lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn àti àbáraẹni sọ̀rọ̀ lójú òpó ayélujára, ọ̀gbẹ́ni Bayọ Akande fọwọ́ ìdánilójú sọ̀yà pé, ilésẹ́ náà ti setán fún sísàmúlò ìsèjọba nílànà ìgbàlódé.

AdebisiAfọnja