Yoruba

Ile Igbimo Asofin Ipinle Oyo, ti so pe iro to jinna sooto ni oro kan to n tan kaakiri pe, ile asofin naa fe yo igbakeji gomina, Ogbeni Rauf Olaniyan ti won si sapejuwe aheso oro naa gege bi igbese lati si araalu lona.

Nigba to n soro lori oro ohun, Alaga igbimo tekoto’le feto ibaraenisoro, iroyin ati timo ero, Ogbeni Kazeem Olayanju salaye pe, iroyin ti kii se ododo ohun ba Ile Asofin naa lejafu tesi yanmilenu pupo.

Bee lo wa seedi mimo pe ko si igba tabi akoko kankan t’ile Asofin naa joko lati jiroro lori iru fe igbese.

Mosope Kehnide/Folakemi Wojuade

Yoruba

Ile Igbimo Asofin Ipinle Oyo ti gba Igbimo alase nimoran pe ki won wo bi oju ojo se ri nipa ajakale arun Covid-19 ki won to si awon ile-iwe pada gege bi won se ngbero re.

Eyi lo waye nipa bi oro naa se nile igbese kiakia wipe aba ti omo ile Asofin naa ti n soju ekun idibo Guusu Iwooorun Ibadan keji, Ogbeni Oluwafemi Fowokanmi tepepe re pe kile asofin naa da ileese eto eko lowo ko lori siside awon ile eko aladani ti ko tii foruko sile pelu Ijoba.

Opo awon omo ile asofin waa bi igbakeji Adari ile Asofin Ogbeni Mohammed Fadeyi at adari owo egbe Oselu to pojulo nile asofin naa, Ogbeni Sanjo Adedoyin salaye pe, pelu biye awon to fara kaasa arun naa se tip o sii n’ipinle Oyo Igbimo alase nilo lati gba oro awon ewe yewo.

Awon asofin naa ro ileese eto eko pe ki won lekun ninu igbiyanju won lati dena ajakale aarun Covid-19 pelu ririi daju pe gbogbo ilana ti won fi lele lo je titele kawon ileewe o to e je sisi pada.

Adari ile, Ogbeni Debo Ogundoyin kesi ileese eto eko pe ki won rii daju pe awon ileewe ti to forukosile pelu ijoba se atunse to yen nipa bibere eto iforukosile ileewe won ni kiakia, ki won si tele ilana to ndena itankale arun Covid-19.

Ile asofin naa wa buwolu iyansipo Aajagunfeyinti Ajibola Toogun ati Ajagunfeyinti Olayinka Olayanju gege bi alaga at Oludari Iko Alaabo Amotekun n’ipinle Oyo.

Yoruba

Adarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ Ọyọ, ọ̀gbẹ́ni Debọ Ogundoyin ti gba alága àtàwọn ìgbìmọ̀ tẹkótó ilé ẹlẹ́ni márùndínlọ́gbọ̀n níyànjú láti sisẹ́ wọn bí isẹ́.

Adarí ilé gbé àmọ̀ràn yíì kall lákokò tó ńbura fún ìgbìmọ̀ náà níbi ètò kan èyí tí pínpín ìwé òfin àtẹ̀lée fáwọn ìgbìmọ̀ ọ̀hún tí wáyé níbẹ̀ pẹ̀lú.

Ó sàlàyé pé ojúse àti ìgbésẹ̀ ìgbìmọ̀ yíì sepàtàkì fún ìfẹsẹ̀múlẹ̀ asori ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ Ọyọ.

Nínú ọ̀rọ rẹ̀, asojú tẹ́lẹ̀ nílé-ìgbìmọ̀ asojú sòfin, ọ̀mọ̀wé Wale Okediran sọpé ìgbìmọ̀ ilé ma ńsisẹ́ tó sísegbẹ́kẹ̀lé àwọn ohun tó se pàtàkì jùlọ fún ilé bí síse àgbéyẹ̀wò, ìdúró-réè, àti sósọ àbá dòfin láti sètò ìjọba nípinlẹ̀.

Kemi Ogunkọla/Mosope Kẹhinde