Yoruba

Ile Asofin Gba Ijoba Nimoran Lori Sisi Ileewe Pada N’ipinle Oyo

Ile Igbimo Asofin Ipinle Oyo ti gba Igbimo alase nimoran pe ki won wo bi oju ojo se ri nipa ajakale arun Covid-19 ki won to si awon ile-iwe pada gege bi won se ngbero re.

Eyi lo waye nipa bi oro naa se nile igbese kiakia wipe aba ti omo ile Asofin naa ti n soju ekun idibo Guusu Iwooorun Ibadan keji, Ogbeni Oluwafemi Fowokanmi tepepe re pe kile asofin naa da ileese eto eko lowo ko lori siside awon ile eko aladani ti ko tii foruko sile pelu Ijoba.

Opo awon omo ile asofin waa bi igbakeji Adari ile Asofin Ogbeni Mohammed Fadeyi at adari owo egbe Oselu to pojulo nile asofin naa, Ogbeni Sanjo Adedoyin salaye pe, pelu biye awon to fara kaasa arun naa se tip o sii n’ipinle Oyo Igbimo alase nilo lati gba oro awon ewe yewo.

Awon asofin naa ro ileese eto eko pe ki won lekun ninu igbiyanju won lati dena ajakale aarun Covid-19 pelu ririi daju pe gbogbo ilana ti won fi lele lo je titele kawon ileewe o to e je sisi pada.

Adari ile, Ogbeni Debo Ogundoyin kesi ileese eto eko pe ki won rii daju pe awon ileewe ti to forukosile pelu ijoba se atunse to yen nipa bibere eto iforukosile ileewe won ni kiakia, ki won si tele ilana to ndena itankale arun Covid-19.

Ile asofin naa wa buwolu iyansipo Aajagunfeyinti Ajibola Toogun ati Ajagunfeyinti Olayinka Olayanju gege bi alaga at Oludari Iko Alaabo Amotekun n’ipinle Oyo.

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *