Yoruba

Àjọ ton mojuto idagbasoke eto ìlera alabode nipinle Ogun pẹ̀lú ifowosowopo ìgbìmò tó ń risi ọrọ ìlera ojú nipinle náà tí sàgbékalè ètò ayẹwo ojú lofe fáwọn onimoto, ero àtàwọn aladani láwọn ibùdóko jákèjádò ìpínlè náà gẹ́gẹ́bí ara eto ton sàmìń ayajo ọjọ́ iriran tóko lọ́dún yi.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àkòrí todun yi, tii se “nifẹ ojú rẹ, doola ẹ̀mí”, nibi ètò náà tó wáyé nilu Abeokuta, alága ẹgbẹ́ àwọn olùtọ́jú ojú eka tipínlè Ogun  Dókítà Oladapo Awodein ṣàlàyé pé igbelewon tí fihàn pé bí idà lọ́nà adota ìjàmbá ọkọ̀ ton wáyé je nípasẹ̀ airíran, idi niyi tó lómú ṣe kókó láti dojú kọ àwọn onímòto.

Nínú idasi alaga ẹgbẹ́ àwọn onímòto Igun Road Transport Employees Association of Nigeria ní Kútò, Olóyè Lanre Ladipo gbóríyìn fún ìjọba ìpínlè Ogun ló rii mímú ìtọ́jú ohun àbò àwọn onímòto lọkúkúndun pẹ̀lú ríro àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ẹ láti máa ṣètọ́jú ojú wọn boseto.

Alamu/Olaopa

Subscribe to our Telegram Channel and join our Whatsapp Update Group

Yoruba

Ijoba Ipinle Ogun ti fi ipinnu re han lati mu atunto to wuyi de ba eka irin ajo afe atawon gbongan asa ibile pelu eron gba lati je  kowo to nwole si akoto oba nipinle ohun ko tubo rugoogo sii.

Alamojuto foro asa ati irin ajo afe nipinle Ogun Arabinrin Motunrayo Adeleke Oladapo lo siso loju oro oun lakoko too nforowero pelu akoroyin ileese Radio Nigeria nilu Abeokuta.

Arabinrin Motunrayo Oladapo eni to salaye pe,  eleda fi opolopo ibudo irin ajo afe  jinki ipinle Ogun bii, gbongan asa june 12, Ori Oke Olumo ati ibudo iyawe kawe Olusegun Obasanjo.

O salaye siwaju pe, akitiyan ti nlo lowo lati mu atunto to loorin  ba eka irin ajo afe nipinle naa.

Arabinrin Oladapo tenumo pe, ipinle Ogun lo nle waju ninu awon ipinle gbogbo leka eto asa,paapajulo nidi ipese aso adire.

Nigba to nsoro lori ayajo asa lagbaye fun ti Odun yi, alakoso  ro eka aladani lati fowosopo pelu ijoba Ipinle lati mu eka yi dun wo fun awon araalu.

O tun woye pe, irufe igbese oun,yoo je ki awon aralu  ni ife sawon ibudo irin ajo afe nipinle naa ati pe yoo tun ni ipa to dara lori oro aje ipinle naa.

    Olukemi Ogunkola

Subscribe to our Telegram Channel and join our Whatsapp Update Group

News Yoruba

Gegebi are isapa lati mu ilosiwaju ba yiyanju aawo ati eto idajo nipinle ijoba ipinle Ogun ti sefilole ajo ti yio maa risi ilana ati maa gbe eto idajo kale tipinle.

Nigbati o nsoro nibi ayeye ifilole naa to waye ni gbongan awon lobaloba to wa l’oke Mosan nilu Abeokuta, Gomina Dapo Abiodun salaye wipe liana naa bi won ba samulo re yio fun ijoba ni anfani ati mo awon aini awon eniyan lori idajo ati wa ona ati yanju won.

Gomina Abiodun toka sii wipe be won ba fie to sori awon ara ilu yio muki gbogbo eniyan ni anfani kan naa si eto idajo.

Ninu oro re, adajo agba nipinle Ogun Onidajo Mosunmola Dipeolu so wipe eka eto idajo nipinle Ogun ni owo fun awon oro to jemo tara ilu to wa toka sii wipe won ti setan ati rii daju wipe won fi igbejo fale rara.

Adesida/Dada

Yoruba

Gomina Ipinle Ogun, Omo Oba Dapo Abiodun n bere fun atileyin ijoba apapo lati se iranwo fun awon olugbe ere kusu Tongeji nibi ti epo roobi wa.

O soro yi nilu Abeokuta, lasiko iside apero olojo mejii eyi ti ileese to mojuto alaa ile nile yi ati lekun gusu iwoorun seto re.

Gomina Abiodun tokasi pe, isejoba oun mo pe oseese ki epo roobi wa ni erekusu naa, idi niyi teto igbayegbadun awon eeyan ibe sese Pataki.

Saaju ni oludari ajo to n mojuto oro alaa, ogbeni Adamu Adaji so pee to apero naa, ni won se agbekale re kawon torokan, to n mojuto alaa ayika ile yi le gbe liana atele kale ti yo yanju awon ipenija to seese to suyo

Adesida/Afonja

Yoruba

Awọn agbe ati awọn darandaran ni ilu Eggua ti fẹnuko ati gbe igbimo dide lati máa wá ojutu sí orísirísi fàá kaja to ma na waye.

Igbimo ohun ni o ni awọn agbe, awọn darandaran, ati awọn agbofinro, ti yóò sì wa lati ma dènà ija ajaku akata to ma ni waye lodoodun.

Awọn igun mejeeji fi enu ohun ko nibi ipade kan ti won se nilu Tata, Ijoba Ibile Ariwa Yewá pelu awon igbimo ti Ijoba Ipinle Ogun gbe dide lori oro naa.

Àkoroyin wa Wale Oluokun ni ekunrere iroyin naa lowo.

Yoruba

Won ti se agbende Iko alaabo alajumose nipinle Ogun lati fir ii daju pe ko seni to tapa sofin, ati fun ipese aabo emi ati dukia jakejado ipinle naa.

 Gomina ipinle Ogun, Omooba Dapo Abiodun lo sipaya oro yi loju opo ikanni abeyefo re (tweeter) nibi to tun ti ro gbogbo araalu pe ki kaluku o maa ba ise oojo won lo lai foya tabi sojo.

 O tun sekilo fawon arijagba to gba iwode woorowo mo awon to n fehonu han lowo pe ki won yago fun pipagidana eto irina to ja gaara, ati bi won se n fe maa ba dukia ijoba ati taladani je.

 Salaudeen

Yoruba

Ijoba ipinle Ogun ti ni ohun yio ko ile alaboode toto egberun meji abo fun awon olugbe ipinle Ogun laarin odun meta to nbo.

Gomina ipinle Ogun Omoba Dapo Abiodun eniti o soro yi di mimo nilu Abeokuta lasiko ayeye ojo ibugbe lagbaye ni isapa ijoba yio yanju awon ipenija aito ilegbe.

O ni ipinle naa ti nfowosowopo pelu ijoba apapo lati pese ileegbe toto egberun mewa nipinle naa lati mun adinku ba ipa ti ajakale arun covid-19 ni.

Alakoso foro ato ilu nipinle naa, Ogbeni Olayunji Odunlami ni ayeye naa yio jeki ijoba ati awon toro kan gbongbon wa ona lati mu idagbasoke baa won ilu nla nal ati awon igberiko nidi ipese ilegbe alabode fun awon eniyan.

Akori ayeye todyn yi ni “ilegbe fun gbogbo eniyan, ojo iwaju to tubo dara fun awon ilu nla” ni  o bojuwo ona lati la awon eniyan loye lori oro ilegbe ati akitiyan lati pese ile gbe alaboode fun awon eniyan jakejado agbaiye.

Oluokun/Dada

Yoruba

Ipinle Ogun naa ti ni ipin tirẹ ninu awọn iṣẹlẹ ifipa banilo káàkiri ilẹ wa.

Lat’ori iṣẹlẹ ti ọkunrin omo odun metadin lógbón kan to fi ipa ba iya agba eni ogorin odun lo nitipatipa ati ti ọkunrin omo odun meedogbon to gbiyanju ati gbemi eniti ofi ipabalo titi dé orí oluko ile iwe gírámà kan to ni ibalo lọnà aito pẹlu akeko re kan omo odun merinla, ounka naa ko niye mo. 

Akoroyin wa Wale Oluokun ninu akanse iroyin yin fi ojú wo bi isele ifipabanilopo ṣee n losoke ati ona tiwon le lo latifi wa adinku ba iṣẹlẹ naa.