News Yoruba

Ìjọba àpapọ̀ ti fìdùnú rẹ̀ hàn lórí bí ilẹ̀ gẹ́ẹ̀sì se yọ ilẹ̀yí kúrò nínú ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀èdè téwu àjàkálẹ̀ àrùn wà nílẹ̀ àgbáyé pẹ̀lú bí wọ́n se fòpin de balù ilẹ̀yí láti máse wọ ìlú gẹ́ẹ̀si nípasẹ̀ ìbẹ́sílẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn Omicron tẹlẹ.

Ọga àgbà ẹ̀ka ìkànsáralu nílé isẹ́ tón rísí ìgbìkègbodò òfurufú, Dókítà James Odaudu tó sọ̀rọ̀ náà lásìkò tón fọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú àwọn oníròyìn, sọpé àwọn koti rí ìwé kankan gbà láti ilẹ̀ gẹ́ẹ̀sì lórí bí wọ́n se yọ ilẹ̀yí kúrò nínú orúkọ àwọn orílẹ̀èdè téwu àjàkálẹ̀ àrùn wa níbẹ̀.

Láti arọ òní lọ, ni àwọn alásẹ ilẹ̀ gẹ́ẹ̀sì ti kéde yíyọ ilẹ̀ Nàijírìa àtàwọn orílẹ̀èdè mẹ́wa min nílẹ̀ Afrika kúrò nínú orúkọ àwọn tí wọ́n fòfin ìrìnà dè pẹ̀lú fífáàyè gba ìwọlé wọ̀de àwọn arìnrìnajò láti wọlé náà.

Ọrọ náà lótẹ̀lé bí ilẹ̀yí se kéde pé òhun yo gbe ìgbésẹ̀ ti yóò jẹ́kí ilẹ̀ gẹ́ẹ̀sì. Ilẹ̀ Canada, àti ilẹ̀ UAE, gbẹ́sẹ̀ kurò lórí òfin tófide ilẹ̀ yí.

Fadahunsi / Ọlaọpa

News Yoruba

Wọ́n ti rọ ìjọba àpapọ̀ láti sàgbékalẹ̀ àwọn òfin kan tí yóò pa abẹ́rẹ́ àjẹsára ní dandan fáwọn ògo wẹrẹ, lọ́nà àti dábobo wọn kúrò lọ́wọ́ àwọn àrùn àtàisàn lọ́kọ́kan òjọ̀kan.

Akọ̀wé àgbà àjọ tón bójútó ètò ìlera alábọ́dé nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ Dókítà Muyideen Ọlatunji ló sọ̀rọ̀ yíì di mímọ̀ lákokò tónkópa lórí ètò ọlọ́sọ̀ọsẹ̀ ilé-isẹ́ wa kan lédé gẹ́ẹ̀sì tapèní, Stright talk níkànnì Premier F.M. 93.5.

Dókítà Ọlatunji tọ́kasi pé, bí ìgbésẹ̀ gbígbà abẹ́rẹ́ àjẹsára bá jẹ́ dandan fáwọn ọmọdé, yóò mádinkù báwọn ìpèníjà táwọn òsìsẹ́ elétò ìlera máà dojúkọ lákokò tíwọ́n bá lọ sójúlé dójúlé fétò abẹ́rẹ́ àjẹsára náà ní gbígbà.

Ó wá gbàwọn òbí nímọ̀ràn láti ridájú pé, àwọn gba gbogbo abẹ́rẹ́ àjẹsára èyí tó lẹ́tọ fáwọn ọmọ wọn láti gbà láida ọkan sí nínú rẹ̀, láti dènà àwọn àrùn tó máà ń pa ọmọdé ní rèwerèwe.

Ó tẹnumọ pé, láti le jẹ́ kórílẹ̀dè yíì, jàjàbọ́ lọ́wọ́ àisàn rọmọlápá rọmọ lẹ́sẹ̀, àmójútó tó péye gbọ́dọ̀ wà fétò abẹ́rẹ́ àjẹsára nígbígbà.

Dókítà Ọlatunji wá gbàwọn èèyàn níyànjú láti gbabẹ́rẹ́ àjẹsára èyí tó wà fún àrùn covid-19 kíwọ́n sì tẹpẹlẹmọ́ pipawọn òfin àti ìlànà ètò ìlera rẹ̀ mọ́ọ̀.

Okareh/Wojuade

News Yoruba

Alákoso fọ́rọ̀ abẹ́lé, ọ̀gbẹ́ni Rauf Arẹgbẹsọla ti sọpé ìjọba àpapọ̀ yóò sisẹ́ lórí àwọn ọ̀daràn tó n sèkọlù sí àwọn òsìsẹ́ panápaná àti àwọn dúkia ilé isẹ́ náà jákèjádò ilẹ̀ Nàijírìa.

Ọgbẹni Arẹgbẹsọla yọjú ọ̀rọ̀ náà síta lásìkò tón sísọ lójú ọkọ̀ panápaná olówó iyebíye tuntun tíjọba àpapọ̀ kó lọ sílé isẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Taraba nílu Jalingo.

Ó sàlàyé pé, ìjọba àpapọ̀ ní kòní fàyè gba àwọn ọ̀daràn tón man sèkọlù ohun bíba dúkia àjọ náà tó wà fún dídáàbò bo ẹ̀mí àti dukia àwọn aráàlu lọ́wọ́ ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbá iná jẹ́mọ́.

Alákoso ọ̀hún sàfikún àlàyé rẹ̀ pé, èrè ìdí kíkó ọkọ̀ panápaná ìgbàlódé ohun lọ sípinlẹ̀ Taraba lójẹ́ èróngbà ìsèjọba Arẹ Buhari lórí àtúntò ilé isẹ́ panápaná pẹ̀lú ìfọkànsìn sí isẹ́ ìlú.

Sáàjú ni alámojútó ilé isẹ́ panápaná ìjọba àpapọ̀, ọ̀mọ̀wé Imam Ibrahim ti sàlàyé pé àwọn ọkọ̀ panápaná tuntun ti wọn kó wá sí ìpínlẹ̀ Taraba lójẹ́ àfikún isẹ́ tìjọba ìpínlẹ̀ náà tise.

Ọlarinde/Ọlaọpa

Yoruba

Ìjọba àpapọ̀ ti fẹ́ sèdásílẹ̀ ibùdó ìmọ̀ ẹ̀rọ àti ọgbọ́n àtinúdá mẹ́fà sáwọn ẹkùn ibùdó mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tó wà lórílẹ̀ èdèyí.

Ìgbésẹ̀ yí jẹ́ láti sàmúlò àwọn àbọ̀ isẹ́ ìwádi láti fi pèsè àwọn ohun èlò tó léè tankàngbọ̀n lágbayé.

Alákoso fọ́rọ̀ ìmọ̀ sciensi, ìmọ̀ ẹ̀rọ àri ọgbọ́n àtinúdá, Ogbonnaya Onu, ló sọ̀rọ̀ yí lásìkò tó lọ sàbẹ̀wò sí Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano, Abdulahi Ganduje lórí ìgbésẹ̀ àti sèdásílẹ̀ ibùdó tí yio wà lẹ́kùn ìwọ̀ óòrùn àríwá ilẹ̀ yí sípinlẹ̀ Kano.

Ọgbẹni Onu bu ẹnu àtẹ̀ lu bí wọ́n kíì séè sàmúlò àwọn àbọ̀ isẹ́ ìwádi nítorípé gbogbo àwọn tọ́rọkàn ńdásẹ́ wọn se ni.

Ó wá béèrè fún jíjíròrò papọ̀ láàrin àwọn àjọ tó ńrísí ọ̀rọ̀ isẹ́ ìwádi, lájọlájọ ilé ẹ̀kọ́ gíga àti àwọn ilé ẹ̀kọ́ gbogbo níse bí wọn bá ńgùnlé isẹ́ ìwádi.

Ọlarinde/ Afonja

Yoruba

Ijoba apapo pelu ajosepo banky agbaye, yoo pin egberindinlaadota million dollar ni ipinle merindinlogoji to w anile yi, lati madinku ba ipa aarun covid-19.

Alakoso keji feto isunaa ati aato gbogbo, Ogbeni Clem Agba so eyi nilu Abuja.

O salaye pe, ipinle kokan yoo gba ogun million dollar, nigba tii million medoogun dollar yo je tolu-ilu yii FCT.

Alakoso Agba fikun pe, igbese naa waaye lati mu agbende ba eto oro-aje nibamu pelu mimu ileri Aare Buhari se nidi yiyo million mewa omo ile Nigeria kuro ninu ise ati osi.

Elizabeth Idogbe

News Yoruba

Ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀èdè yíì ti rán ìgbìmọ̀ amúsẹ́yá lọ sípinlẹ̀ Kano, láti ló kápá àisàn pàjáwìrì kan tó bẹ́sílẹ̀ nípinlẹ̀ ọ̀hún.

Olùdarí àgbà pátápátá fún ibùdó tón rísí ìkápá àrùn lọ́lọ́kanòjọ̀kan nílẹ̀ yíì, NCDC, Dókítà Chikwe Ihekweazu ló sísọ lójú ọ̀rọ̀ yíì nílu Abuja lákokò ìpàdé alájùmọ̀se kan tígbìmọ̀ amúsẹ́yá tílesẹ́ àrẹ gbékalẹ̀ covid-19.

Ó sàlàyé pé, ìgbìmọ̀ amúsẹ́yá ọ̀hún yóò sàmójútó àwọn èèyàn bi ìgbà tó tilùgbàdì àisàn náà, pẹ̀lú àwọn èèyàn mẹ́rin tó ti tipasẹ́ rẹ̀ jáde láyé.

Dókítà Ihekweazu kò sài fikun pé, ilé-isẹ́ ètò ìlera ìpínlẹ̀ náà, sọ pé onírunru ẹ̀sùn làwọn tigbọ́ nípa àrùn náà, làwọn ìjọba ìbílẹ̀ bi mẹ́tàlá tón bẹ nípinlẹ̀ Kano, nínú èyí táisan iba, eebi kojú pọ́n àtàwọn èyí tíníse pẹ̀lú inu wa, gẹ́gẹ́bí àwọn àmì tíwọ́n ńrí.

Banjọ/Wojuade

Yoruba

Alákoso fóun abẹ́lé lórílẹ̀dè yíì, ọ̀gbẹ́ni Rauf Arẹgbẹsọla, sọpé aléèkún tó ńbá àwọn arìn-rìn àjò tí wọ́n sètò ìrìnà lọ́nà àitọ́ níì bétò àbò lẹ́nu ìloro se ti mẹ́hẹ.

Alákoso ké gbàjarè yíì, níbi ìpàdé tóse pẹ̀lú àwọn asojú àjọ ìsọ̀kan ilẹ̀ Europe èyítí asójú ilẹ̀ Nàijírìa àti Ecowas, Ketil Karlsen léwájú.

Ó sàlàyé pé ètò ìrìnnà lọ́nà àitọ́ ti di ìpèníjà ńlá sí ìjọba pẹ̀lú bóse ńsàkóbá fétò ìlera àti àwọn ọlọ́pọlọ pípé ẹ̀dá nílẹ̀ yíì.

Ọgbẹni Arẹgbẹsọla sọpé orílẹ̀dè Nàijírìa ńbèrè fún àtìlẹyìn tó gbọgbọ́n látọ̀dọ̀ àwọn tọ́rọkàn láti wójùtú wọn lórí ìlànà àkọsílẹ̀ àwọn arìnrìnàjò.

Idogbe/Afọnja

News Yoruba

Ìjọba àpapọ̀ ti setán láti gba àwọn akẹ́kọ jáde, ilé ẹ̀kọ́ gíga ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n níye sẹ́nu isẹ́ lẹ́ka ètò ọ̀gbìn láti sàtìlẹyìn fáwọn àgbẹ̀ yíká orílẹ̀ èdè yí.

Akọ̀wé àgbà, fún ẹgbẹ́ tón mójútó ètò ọ̀gbìn àti ìdàgbàsókè ilẹ̀, ọ̀gbẹ́ni Paul Ikonne ló sọ̀rọ̀ yí fáwọn akọ̀rìnyìn nílu Abuja pẹ̀lú àlàyé pé àwọn akẹ́kọ jáde yi ni wọn ma se ìdánilẹ́kọ fún lórí ẹ̀ka ọ̀gbìn tófimọ́ gbígbà oníruru ilẹ̀ àti sísàyẹ̀wò rẹ̀.

Oní wọ́n yo gba wọn sísẹ́ lábẹ́ ilésẹ́ tón mójútó àwọn ọ̀dọ́ àgbẹ̀ .

Ó sọ di mímọ̀ pé ìjọba àpapọ̀ ti rọ ọ̀dọ́ àgbẹ̀ tó jẹ́ ogun níye lágbára pẹ̀lú owó tó jẹ́ milliọnu lọ́nà ọgbọ̀n naira pẹ̀lú àfikún pé, bánki tón mójútó isẹ́ àgbẹ̀ ni yo pèsè owó ọ̀hún.

Fadahunsi/Afonja

Yoruba

Ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀dè yíì ti sèkìlọ̀ fáwọn èèyàn àwùjọ láti máà se lọ fi ìbẹ̀rù bojo rọ èrónjà cement sowo, mítorí bówó rẹ̀ seti gbẹ́nusókè láwọn apá ibikan lórílẹ̀dè yíì.

Àtẹ̀jáde kan tílesẹ́ olókóòwò, àti ìdásẹ́ ajé sílẹ̀, fisíta sọpé, ilé-isẹ́ náà ń sisẹ́ takuntakun láti lọ́wọ́ àwọn tọ́rọkàn sẹ́ka tón pèsè, èròjà cement láti fi wójùtú sí ọ̀wọ́n gógó rẹ̀.

Àtẹ̀jáde náà fikun pé, àdínkù tó dé bá ìpèsè cement lábala kejì àti ìtẹ́ta ọdún tókojá nítorí ìbẹ́sílẹ̀ kòkòrò àrùn covid 19, àti ìfẹ̀húnúhàn fífòpin sí ikọ̀ sars tó wáyé, ló mú àkùdé bá ìpèsè cement ọ̀hún.

Kò sài tún sọ́ọ̀di mímọ̀ pé, táwọn èèyàn bá ńra èròjà cement náà pamọ́ kòní bójúmu tó nítorí pé fún gbadiẹ ni iye owó tíwọ́n ńta báyi kònípẹ́ já wálẹ̀ àtàwọn wọn fifọ lórekóòre.

Bẹ́ẹ̀ si látẹ̀jáde náà tún fikun pé, wọ́n gbọ́dọ̀ fẹsẹ̀ òfin ó lo ìbòmú, ó wọlé sáwọn ibùdó bí, ilé óunjẹ ìgbàlódé àtàwọn ibùdó ìgbafẹ́ múlẹ̀ daindain tó fi mawọ ọjà.

Níbàyíná, ìjọba ìpínlẹ̀ náà tíwọ́n sàfikún àwọn ohun èlò àyẹ̀wò rẹ̀ yíká àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tónbẹ nípinlẹ̀ Ọsun.

Banjọ/Wojuade

Yoruba

Ètò àgbékalẹ̀ ilégbe tó jẹ́ ọ̀kan gbogi nídi fífẹsẹ̀ èróngbà ìdúrósinsin ètò ọrọ̀ ajé ilẹ̀ yíì múlẹ̀, làfojúsùn rẹ̀ jẹ́ ìgbésẹ̀ ìrọ̀rùn fáwọn èèyàn tówó tó ń wọlé fún wọn, kó tó ùnkan.

Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fáarẹ Muhammadu Buhari lórí ọ̀rọ̀ ìgbáyégbádù, arábìnrin Imeh Okoh tó fìdí èyí múlẹ̀ nílu Abuja, sọpé, ètò náà kò wà fáwọn olósèlú tàbí àwọn èèyàn tó rọ́wọ́ họrí, bíkòse àwọn èèyàn tígbà kudiẹ káato fún.

Kò sài fi kálàyé rẹ̀ pé, ọ̀kan lára èróngbà ìsèjọba tó wà lóde báyíì ni ìpèsè ilégbe fáràalú yíká orílẹ̀dè yíì, pẹ̀lú àtọ́kasí pé, àwọn ilégbe náà ni yóò jẹ́ ojúlówó, tí yóò sì kójú òsùwọ̀n lai fiti owó péréte tíwọ́n yóò máà gbà lórí rẹ̀ se.

Arábìnrin Okoh tún se lálàyé pé, ètò náà ló wà fáwọn tówó tón wọlé fún wọn ti ìbẹ́sílẹ̀ àrùn covid-19 ti se ìpalára fún.

Aminat/Wojuade

News Yoruba

Ìsèjọba ààrẹ Muhammadu Buhari yóò tẹ̀wáwájú ní di mímọ́rọ̀ ìdàgbàsókè ẹ̀ka ètò ọ̀gbìn lọ́kunkúdùn nípasẹ̀ ètò ìrónilágbára fáwọn ọ̀dọ́ àtàwọn obìnrin tí yóò se kóríyá fún láti fi yan ẹ̀ka ètò ọ̀gbìn láàyo.

Alága ìgbìmọ̀ níbùdó tón rísísẹ́ ìwádi nípa ọ̀gbìn ewébẹ̀, NIHORT, Ajagun fẹ̀yìntì Garba Muhammed, ló sọ̀rọ̀ yíì di mímọ̀ lákokò tó ń síde ètò ìdánilẹ́kọ ọlọ́jọ́ kan lórí ìpèsè ọ̀pẹ̀ òyìnbó fáwọn ọ̀dọ́ àtàwọn obìnrin nílu Ìbàdàn.

 Ọgagun àgbà Muhammed wá sàpèjúwe ìdánilẹ́kọ fáwọn ọ̀dọ́ tí kò nísẹ́ lọ́wọ́ náà, gẹ́gẹ́ bí ara àayan ìjọba àpapọ̀ láti mágbende bá ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀dè yíì.

Sáàjú nínú ọ̀rọ̀ ọ̀gá àgbà ibùdó NIHORT, nílu Ìbàdàn, ọ̀mọ̀wé Abayọmi Ọlaniyan jẹ́jẹ àtìlẹ́yìn ibùdó náà láti pèsè àwọn onímọ̀ tí yóò sisẹ́ papọ̀ pẹ̀láwọn tó jànfàní ètò ìdánilẹ́kọ ọ̀hún, fimu kí ìpèsè ọ̀pẹ̀ òyìnbó tamọ̀sí PineApple rúgọ́gọ́si.

 Mẹ́ta lára àwọn tó jànfàní ètò náà, David Forunso, Ọlaitan Ọlalẹyẹ, àti Dorcas Damilọla gbóríyìn fún ìjọba àpapọ̀, tíwọ́n sì sèlérí pé àwọn yóò sàmúlò ìmọ̀ táwọn ríkọ́ níbi ètò náà dada, táwọn ẹlomin náà yóò sì tún jànfàní látara ìmọ̀ ọ̀hún.

Bí àwọn olùkópa àadọ́ta, nínú èyí tọ́pọ̀ nínú wọn ti jẹ́ ọ̀dọ́ àtàwọn obìnrin ló jànfàní látara ètò ìdánilẹ́kọ ọ̀fẹ́ ọ̀hún lórí ìpèsè ọ̀pẹ̀ òyìnbó.

Kehinde/Wojuade

Yoruba

Àarẹ orílẹ̀dè yíì, Muhammadu Buhari ti tẹnumọ́ ìpinnu ìjọba tó wà lóde báyíì láti fòpinsí báwọn ilé-isẹ́ apínná ká se máà ńbu owó láibítà fáwọn oníbarà wọn nílẹ̀ Nìajírìa.

Àarẹ Buhari tó sọ̀rọ̀ yíì di mímọ̀ nílu Abuja, tó sì sàlàyé pé, ìsèjọba òun yóò ridájú pé, iye iná ọba táwọn ọmọ orílẹ̀dè yíì bá ń lò nìkan ni wọ́n ń sanwó rẹ̀.

Àarẹ kò sài fi kálàyé rẹ̀ pe, ìjọba ti ń gbé ìgbésẹ̀ láti pín àwọn ẹ̀rọ tó ń ka iye iná ọba bi milliọnu kan lọ́fẹ gẹ́gẹ́ bí ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ nínú èyí tó lé ní milliọnu mẹ́fà ẹ̀rọ tó ńka iye iná ọba tóníbarà bá lò tíwọ́n fẹ́ pín yíká orílẹ̀dè yí.

Ololade Afonja

Yoruba

Ìjọba àpapọ̀ ti sọ pé kòsí on ìkọ̀kọ̀ kankan lórí àbá òfin lórí omi èyí tí ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà ńgbé yẹ̀wò lọ́wọ́.

Níbi àpérò kan nílu Abuja ni alákoso fọ́rọ̀ ìròyìn àti àsà, Àlhájì Lai Mohammed àti alákoso fún ọ̀rọ̀ tóníse pẹ̀lú omi, ọ̀gbẹ́ni Suleiman Adamu, sọpé ọ̀pọ̀ àwọn tón kọminú lórí àbá òfin yi, ni wọn kò mọ on pàtó tí yo pèsè tí wọ́n sin gbọ àhesọ ọ̀rọ̀ lẹ́nu àwọn miràn.

Àwọn alákoso méjèjì sọ pé àbá òfin yi ni wọn se àgbékalẹ̀ rẹ̀ láti pèsè àwọn akọ́sẹmọ́sẹ́ ti yo ma mójútó sísàmúlò gbogbo ibi ojúsàn omi fún lílò àwọn èyàn àwùjọ.

Pẹ̀lú àfikún pé, àbá òfin yi, ki se on tuntun.

Àwọn ẹgbẹ́ nínú èyí tatirí ẹgbẹ́ òsìsẹ́ NLC, ni wọ́n ní àwọn kò faramọ́ àbá òfin yi.

kẹhinde/Afọnja

Yoruba

Igbákejì àarẹ orílẹ̀èdè Nàijírìa Yẹmi Ọsinbajo ti fidá àwọn ọmọ ilẹ̀ yíì tó ńtajà lórílẹ̀èdè Ghana lójú wípé ìdájọ́ òdodo yówayé lórí ohun tí wọ́n jìjàdù rẹ̀ pẹ̀lú ìjọba ilẹ̀ Ghana.

Ọjọgbọn Ọsinbajo, ẹnitó sèpàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn asojú ọmọ ilẹ̀ yíì tíwà ni Accra, Ghana fọwọ́ ìdánilójú ìpinu ìjọba àpapọ̀ sọ̀yà, láti dásí ọ̀rọ̀ náà bótitọ́.

Gẹ́gẹ́ bótiwípé, ìjọba yóò ridájúpé òpin débá fífọwọ́líle mú àwọn ọmọ ilẹ̀ yíì jákè-jádò àgbáyé.

Ẹjẹ́kamúwá sí ìrántí pé, ilé ìtàjà àwọn òntàjà ilẹ̀ yíì lórílẹ̀èdè Ghana lójẹ́ títìpa fọ́pọ̀ osúù, nítorí àilesan milliọnu kan dollar tíjọba orílẹ̀èdè náà bèrè fún.

Mnt/idogbe   

Yoruba

Igbákejì àarẹ orílẹ̀dè yíì, ọ̀jọ̀gbọ́ Yẹmi Ọsinbajo sọpé, ìjọba àpapọ̀ ti nì óuń yóò sàtìlẹyìn fún ìlànà sìsanwó osù àwọn olùkọ́ ilé-ìwé aládaní àtàwọn onísẹ́ ọwọ́, láti pinwọ́ ipá tí ìtànkálẹ̀ àrùn covid-19 timì lórí ètò ọrọ̀ ajé wọn.

Níbi ètò àpérò ọlọ́dọọdún tẹ́gbẹ́ àwọn agbẹjọ́rò tónlọ lọ́wọ́ ọgọ́ta irú ẹ̀, lọ̀jọ̀gbọ́n Ọsinbajo ti sísọ lójú ọ̀rọ̀ ọ̀hún, pẹ̀lú àlàyé pé, ìjọba àpapọ̀ ti ní àwọn ilẹ lókanòjọ̀kan làwọn ìpínlẹ̀ mọ́kànlá tónbẹ nílẹ̀yíì láti fi kọ àwọn ilé gbe oníyàrá méjì-méjì fáwọn ọmọ orílẹ̀dè yíì tíwọ́n yóò sì máà ta ni milliọnu méjì-méjì naira fọ́kọ̀ọ̀kan .

Igbákejì ààrẹ kò sai tún se àlàyé pé, akitiyan ìjọba àpapọ̀ ni láti dábòbò isẹ́ fáwọn èèyàn tí ìtànkálẹ̀ àrùn covid-19 ti mú kétò ọrọ̀ ajé wọ̀n pakasọ.

Wojuade    

Yoruba

Olórí òsìsẹ́ nílẹ̀ yí, ọ̀mọ̀wé Fọlasade Yẹmi-Esan ti sọ pé ìjọba àpapọ̀ kò fọwọ́sí àfikún iye ọdún tí òsìsẹ́ yo lò lẹ́nusẹ́ ọba.

Àtẹ̀jáje èyí tí olùdarí fọ́rọ̀ ìròyìn, arábìnrin Ọlawumi Ogunmosunle fisíta tọ́kasi pé olórí òsìsẹ́ kò fọwọ́ irúfẹ́ ìwé yi lára.

Ọmọwe Yẹmi Esan wá rọ àwọn òsìsẹ́ ọba àti àwọn èyàn àwùjọ láti má se àbẹ̀wò sí ojú òpó ayélujára www.ohcsf.gov.ng lórokóre láti mọ̀ pàtó àwọn ìwé àti ìròyìn tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ tó jáde láti ọ́fìsì olórí òsìsẹ́.

Afọnja