News Yoruba

Wọ́n Ti Gba Ìjọba Àpapọ̀ Níyànjú Láti Sàgbékalẹ̀ Òfin Kan Tí Yóò Pa Abẹ́rẹ́ Àjẹsára Gbígbà Ní Dandan Fáwọn Ọmọdé

Wọ́n ti rọ ìjọba àpapọ̀ láti sàgbékalẹ̀ àwọn òfin kan tí yóò pa abẹ́rẹ́ àjẹsára ní dandan fáwọn ògo wẹrẹ, lọ́nà àti dábobo wọn kúrò lọ́wọ́ àwọn àrùn àtàisàn lọ́kọ́kan òjọ̀kan.

Akọ̀wé àgbà àjọ tón bójútó ètò ìlera alábọ́dé nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ Dókítà Muyideen Ọlatunji ló sọ̀rọ̀ yíì di mímọ̀ lákokò tónkópa lórí ètò ọlọ́sọ̀ọsẹ̀ ilé-isẹ́ wa kan lédé gẹ́ẹ̀sì tapèní, Stright talk níkànnì Premier F.M. 93.5.

Dókítà Ọlatunji tọ́kasi pé, bí ìgbésẹ̀ gbígbà abẹ́rẹ́ àjẹsára bá jẹ́ dandan fáwọn ọmọdé, yóò mádinkù báwọn ìpèníjà táwọn òsìsẹ́ elétò ìlera máà dojúkọ lákokò tíwọ́n bá lọ sójúlé dójúlé fétò abẹ́rẹ́ àjẹsára náà ní gbígbà.

Ó wá gbàwọn òbí nímọ̀ràn láti ridájú pé, àwọn gba gbogbo abẹ́rẹ́ àjẹsára èyí tó lẹ́tọ fáwọn ọmọ wọn láti gbà láida ọkan sí nínú rẹ̀, láti dènà àwọn àrùn tó máà ń pa ọmọdé ní rèwerèwe.

Ó tẹnumọ pé, láti le jẹ́ kórílẹ̀dè yíì, jàjàbọ́ lọ́wọ́ àisàn rọmọlápá rọmọ lẹ́sẹ̀, àmójútó tó péye gbọ́dọ̀ wà fétò abẹ́rẹ́ àjẹsára nígbígbà.

Dókítà Ọlatunji wá gbàwọn èèyàn níyànjú láti gbabẹ́rẹ́ àjẹsára èyí tó wà fún àrùn covid-19 kíwọ́n sì tẹpẹlẹmọ́ pipawọn òfin àti ìlànà ètò ìlera rẹ̀ mọ́ọ̀.

Okareh/Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *