Akójanu ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ Ọsun, ọ̀gbẹ́ni Tunde Ọlatunji ti yọ̀nda ara rẹ̀, láti máà kọ́ àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ ní ẹ̀kọ́ ìsirò àti ẹ̀kọ́ nípa ìbásepọ̀ ẹ̀dá, ojúse àtẹ̀tọ́ aráalu tamọ̀sí, Civic Ẹducation láwọn ilé-ẹ̀kọ́ tó wà lẹ́kùn ìdìbò rẹ̀.

Ọgbẹni Ọlatunji ló sọ̀rọ̀ yíì lákokò tó ń báwọn akẹ́kọ àtàwọn olùkọ́ sọ̀rọ̀ lórí èróngbà rẹ̀ láti máàkọ́ àwọn akékọ́ọ́ ilé-ìwé giramaAnglican Ẹdun-Abọn níjọba ìbílẹ̀ àríwá ifẹ̀, nípinlẹ̀ Ọsun.

Ó fikún àlàyé rl pé, òun yóò kọ àwọn ẹ̀kọ́ méjèjì náà fún sáà ètò ẹ̀kọ́ 2019/2020.

Gẹ́gk bóse wípé, èróngbà oun yíì lóníse pẹ̀lú kínkín akitiyan àwọn olùkọ́ lẹ́yìn àti láti lo ipò rẹ̀, fi se kóríyá fáwọn akẹ́kọ́ọ̀ kíwọ́n ba lè fífẹ̀ hàn sáwọn isẹ́ méjèjì tó ń fẹ́ máà kọ́ wọn.

Ọgbẹ́ni Ọlatunji sàlàyé pé, ètò ìkọ́ni náà ló n pe ni, “Tunde ńlọ kọ́ni Tunde goes to Teach” ni yóò máà wáyé ní gbogbo ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ yíká àwọn ilé-ẹ̀kọ́ tó wà lẹ́kùn ìdìbò rẹ̀ àti ìlú Òsogbo ti sólùùlú ìpínlẹ̀ náà, kò sài fikun pé, àwọn ètò ẹ̀kọ́ kíkọ́ min-in tó n ti gbékalẹ̀ sẹ́yìn ti sèrànwọ́lọ́ fọ́pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó lẹ́bùn lọ́lọ́kanòjòkan àtere ìdárayá yíká ìpínlẹ̀ náà, ni nìkan bí ọdún mẹ́rin sẹ́yìn.

Nígbà tó ń náà sọ̀rọ̀, olórí òsìsẹ́ nípinlẹ̀ náà, ọ̀mọ̀wé Oyebade Olowogboyega gbóríyìn fún asòfin Ọlatunji fún ìgbésẹ̀ akin tó gbé.

Alamu/Dada 

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *