ẹgbẹ́ òsèlú PDP ti lóun kò faramọ́ èròngbà àarẹ Muhammadu Buhari láti dá àwọn ẹnu ìloro tó wọ àwọn ojú òpópónà márosẹ̀ ile yíì padà.

Nínú àtẹ̀jáde kan tíwọ́n fi síta fáwọn oníròyìn nílu Abuja lèyí ti jẹyọ, látọ̀dọ̀ akọ̀wé àgbà fétò ìròyìn ẹgbẹ́ òsèlú PDP, ọ̀gbẹ́ni Kọla Ọlọgbọndiyan, ẹgbẹ́ òsèlú náà wá kọminú pé, àtúgbédìde ẹnu ìloro náà kò bójúmu tó pẹ̀lú ìpèníjá tón kojú ètò ọrọ̀ ajé lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ yíì.

Wọ́n ní dípò bẹ́ẹ̀, ìgbésẹ̀ tágbega yóò fi dé bá ìgbáyé gbádùn ètò ọrọ̀ ajé òhun ètò amúludùn ló yẹ kójẹ́ gbígbé yíká orílẹ̀dè yíì.

Ọgbẹni Ọlọgbọndiyan wá rọ ìjọba àpapọ̀ láti wá ọ̀nà min-in fi wá ọrọ̀ látara àwọn ohun àmúsọrs tón bẹ nílẹ̀ yíì, láti mú kí ìgbéáyádùn gbé fáwọn ọmọ orílẹ̀dè yíì.

A ó ránti pé, ọdún 2003 ni fòpinsí gbígba owó ẹnu ìloro ọhún, èyí táarẹ tẹ́lẹ̀rí, olóyè Olusẹgun Ọbasanjọ pàsẹ rẹ̀.

Kẹmi Ogunkọla/Fadahunsi

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *