Ẹgbẹ́ òsìsẹ́ lápapọ̀ ilẹ̀ yíì, NLC, áti TUC, sọ pé, àwọn kò le sọ ìgbà tàbí àkókò táwọn òsìsẹ́ filè se àfaradà suuru bí ìjọba àpapọ̀ bá kọ̀ láti sàmúlò owó osù tuntun àwọn òsìsẹ́ tó kéré jùlọ títí ọjọ́ kẹrìndílógún osù yíì.

Wọ́n ní gbogbo bí mímú àtúnse dé bá ìlànà sísan owó náà tíì se ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n náirà se ńfalẹ̀, gbọ́dọ̀ jẹ́ títètè wójùtú sí láarin ọ̀sẹ̀ kan gbáko.

Èyí ló jẹyọ nínú àtẹ̀jéde kan, táarẹ ẹgbẹ́ NLC, ọ̀gbẹ́ni Ayuba Wabba, àtàrẹ TUC, ọ̀gbẹ́ni Quadri Ọlalẹyẹ fisíta nílu Abuja.

Àtẹ̀jáde náà tún fikun pé, iye tí ìjọba àpapọ̀ lóun lágbára láti san fáwọn òsìsẹ́ tó wà nípele àkóso isẹ́ keje sí ìkẹrìnlá àti ikẹdógún sí ìkẹtàdínlógún kòse àtkwọ́gbà rara fáwọn òsìsẹ́ ilẹ̀ yíì.

Ẹgbẹ òsìsẹ́ náà kò sài fikun pé, àwọn òsìsẹ́ tó wà nípele àkàsọ̀ keje síkẹrìnlá gbọ́dọ̀ gba ẹ̀kúnwó ìdá mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, nígbà táwọn òsìsẹ́ nípele àkàsọ̀ kẹdógún sí ìkẹtàdínlógún gbọ́dọ̀ gba ẹ̀kúnwó ìdá mẹ́rìnlélógún gẹ́gẹ́ bí owó osù tuntun fáwọn òsìsẹ́.

Kẹmi Ogunkọla/Ibomor

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *