Wọn ti gba olori orilẹ ede yii Muhamadu Buhari nimọran lati fidi ilara iṣẹ idagbasoke to nilo fawọn araalu mulẹ eleyi to ti n ṣe bọ lati bi ọdun mẹta ati abọ sẹyin.

Olukọ ile ẹkọ Varsity Ibadan lẹka imọ ẹkọ ọrọ oṣelu, ọmọwe Dhikrulai Yagboyaju lo gba aarẹ nimọran yii nigba to n sọrọ lori atunyan aarẹ Muhammadu Buhari gẹgẹ bi ajọ eleto idibo apapọ ilẹ wa ṣe kede rẹ.

Ọmọwe Yagboyaju nigba to nki awọn eeyan orilẹ ede yii ati Aarẹ ilẹ yii ku oriire aṣeyọri wọn nigba to rọ Aarẹ Buhari lati tubọ ṣiṣẹ lori ipin yẹleyẹle eto ọrọ aje, ko si jẹki aje le mutumuwa lọrun.

Onimọ ọrọ oṣelu yii tun gba awọn oloṣelu nimọran lati ṣiṣẹ ni tọmọtiya pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari ninu saa keji rẹ, ki wọn le ṣeṣe takuntakun ti yio gbe orilẹ ede yii deebute ogo.

Ogunkọla

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *