Yoruba

Ìjàmbá ọkọ̀ gbemi ẹni márùn-ún nilu Ìbàdàn

Èèyàn márùn-ún ló salabapade ikú òjijì looro òní l’ágbègbè Ìyàna Aleshinloye nilu Ibádán.

Ìròyìn fi díè múlẹ̀ pé ọkọ akeru kan tó ń gbé on mímu, ló sọ ìjánu rẹ nù tó sì rolu ọkọ̀ micra, kó tó di wípé ó wọ inú kọ́kọ́ níyàna aleshinloye.

Àwọn akoroyin iléṣe Radio Nàìjíríà, Modupe Toba àti Dayo Adelowo tí wọ́n wà níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, jabo pe àwọn òṣìṣẹ́ iléṣe tó ń mojuto lílọ bíbo ọkọ̀, àwọn òṣìṣẹ́ iléṣe Ọlọpa, àjọ abo ara ẹni labo lu NSCDC, àti àjọ èso ojú pópó FRSC, lowa níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà láti doola àwọn tó wà lábẹ́ ọkọ̀ akeru ńlá ohùn.

Àwọn tó ń báwọn èyàn kẹ́dùn níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wá ráwọ ẹ̀bẹ̀ sí jọba láti wojutu sirufe ìṣẹ̀lẹ̀ yi, kó ma di lemolemo.

Ẹ̀jeká mú wá sírantí yín pé irúfé ìjàmbá yi wáyé lọ́dún tó kọjá, lógangan ibi tí ìjàmbá tí wáyé loni yi. 

Ololade Afonja

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *