Agbẹnusọ fún ilésẹ́ ọlọ́pa nípinlẹ̀ ọ̀yọ́,ọ̀gbẹ́ni Olugbenga Fadeyi sọpé, ìwádi ti bẹ̀rẹ̀ lórí ìsẹ̀lẹ̀ ìjàmbá iná, tó jó apá ibìkan ilé Sunday Adeyẹmọ, ti gbogbo èyàn mọ̀ sí Sunday Ìgbòho lágbègbè Sókà nílu’bàdàn láfẹ̀mọ́jú òní.

Ọgbẹni Fadeyi sọ pé, wọ́n gba  abọ láti ilésẹ́ ọlọ́pa tó wà lágbègbè Sányò pé àwọn kọ̀lọ̀rọ̀sí èyàn kan tó gbé ọkọ̀ busi Hummar àti micra ni wọ́n ńyìnbọn tí wọ́n sì dáná sun ilé ọ̀hún.

Ọgbẹni Fadeyi wá késí àwọn èyàn àwújọ láti fi ọ̀rọ̀ tó le ran ilésẹ́ ọlọ́pa lọ́wọ́ sọwọ́ kọ́wọ́ lé tẹ̀ àwọn tó wà lẹ́yìn ìsẹ̀lẹ̀ burúkú yi.

Méjì lára, mọ̀lẹ́bí Sunday ìgbòho tíwọ́n ko fẹ kíwọ́n dárúkọ wọn, tísẹ̀lẹ̀ náà sojú wọn, sàlàyé pé àwọn kọ̀lọ̀rọ̀sín ẹ̀dá wọ̀nyí, ni wọn gbé ìbọn lọ́wọ́ lọ́sìkò tí wọ́n sọsẹ́ yí.

Níbàyíná ọ̀gbẹ́ni Sunday Adeyẹmọ nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú akọ̀ròyìn sọ pé ìjàmbà iná ọ̀hún ló bana dúkia towo rẹ jẹ ọpọ milliọnu naira.

Ilésẹ́ Radio Nigeria wóòye pé ilésẹ́ panápaná nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ elola ìsẹ̀lẹ̀ náà ko le ma tanka kiri.

Oluremi/Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *