Àjọ tón rísí ètò ìdánwò gíga ti fòfinde gbígba akẹ́kọ́ọ̀ yowu wọlé sáwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga tón bẹ nílẹ̀ yíì lai lọ́wọ́ òhun nínú, laifi ti ìpele ẹ̀kọ́ yóòwù se.

Olórí ẹ̀ka tón rí sọ́rọ̀ ìròyìn àtàgbékalẹ̀ ìlànà lájọ Jamb, ọ̀mọ̀wé Fabian Benjamin ló kéde yíì nínú ìwé ìròyìn ọlọ́sọ́ọ̀sẹ̀ wọn tíwọ́n fisíta nílu Abuja.

Ọmọwé Benjamin sàlàyé pé, àjọ náà tún fìfinde ètò ìgbaniwọlé alalumọkọrọyii, táwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga kan máà ń se, kó tó dipé, wọ́n yóò gbàwọ́n wọlé ní sansan.

Kò sài tọ́kasi pé, láti àkókò yíì lọ, gbogbo ètò ìgbaniwọlé séyikeyí àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga gbọdọ̀ máà gba ọ̀dọ̀ àjọ Jamb kọja, tó sì sèkìlọ̀ fáwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga náà láti máà fọwọ́ pa idà òfin ọ̀hún lójú.

Bẹ́ẹ̀ ló fikun pé, àjọ náà kò ní fàyè gba, ìgbésẹ̀ gbígbàwọ́n akẹ́kọ́ọ̀ wọlé séyikéyi ilé-ẹ̀kọ́ gíga lọ́nà tí kò bófinmu.

Alamu/Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *