Yoruba

Igbayégbádùn mùtúmuwà lójẹ mi logun – Àarẹ Buhari

Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ọ̀rọ̀ pẹ̀lú àlàyé, èyí ló kí ààrẹ Muhammadu Buhari fójú ọ̀rọ̀ pe, àsẹ ẹ̀ dáwó gbígbé owó ilẹ̀ òkèèrè kalẹ̀ fáwọn tó ńkàn tẹn ńjẹ́ wọlé sílẹ̀ yíì, tó ún pa fún bánki àpapọ̀ orílẹ̀èdè yíì, kò se lẹ́yìn ìgbìyàjú ìjọba láti mú ìdàgbàsókè bá ẹ̀ka ètò ọ̀gbìn kí ìpèsè òunjẹ lánitó àti ànísẹ́kù le rẹsẹ̀ múlẹ̀ nílẹ̀ Nàijírìa.

Ìlú Daura nípinlẹ̀ Kastina lárẹ Buhari ti sọ èyí di mímọ̀, pẹ̀lú àfikún wípé, ìgbéyégbádùn mùtúmuwà ni yo jẹ àkóso rẹ̀ logun ni sáà kejì yíì, nípa síse ètò ìgbé ayé ìrọ̀rún fáwọn tí kò rọ́wọ́họrí láwùjọ.

Àarẹ orílẹ̀èdè yíì wípé owó ilẹ̀ tílé ńrejọ pamọ́ sínú àsùnwọ̀n òkèèrè rẹ̀, nìjọba yóò mu lò láti sètò ìgbélárugẹ ètò ọrọ ajé ilẹ̀yí nípa sísàmúlò àwọn ẹ̀ka miràn tàtọ̀ sí tepo rọ̀bì nìkan, tó sì jẹ́ wípé irú owó bẹ́ẹ̀ kò níjẹ́ lílò mọ fún ọrọ ànko óúnjẹ wọlé láti ilẹ̀ òkèèrè.

Àarẹ tọ́ka sí wípé àwọn ìpínlẹ̀ bíì Kẹbbi, Ogun, Lagos, Jigawa, Ẹbọnyi àti ìpínlẹ̀ Kano, tí sàmúlò ìlànà àgbéga ọ̀tun t;i ìjọba àpapọ̀ là kalẹ̀ fún ìgbélárugẹ ẹ̀ka ètò ọ̀gbìn fún ìpèsè òunjẹ lọ́pọ̀ yanturu àti mímú ìgbé ayé rọrùn fún tolórí tẹlẹ̀mù nílẹ̀ Nàijírìa.

Babatunde Tiamiyu/Net 

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *