Yo dára tí gbogbo àwọn èyàn àwùjọ bá fọwọ́sowọ́pọ̀ láti se àtúntò àwọn nílẹ̀ yi, níbamu pẹ̀lú èyí tíyo se arálu lánfání, fún ọjọ́ iwájú tó dára.

Àrẹ àjọ tón mójútó áàtò ìlú, ọ̀gbẹ́ni Lekwa Ezutah ló sọ̀rọ̀ yi lásìkò ìsíde ayẹyẹ ìpàdé àpérò àdọ́ta irú rẹ̀, àti ìpàdé olọ́dọdún nílu’bàdàn.

Ọgbẹ́ni Ezutah, ẹni tó sàlàyé àwọn ànfàní tó rọ̀ mọ́ síse àtò ìlú lọ́nà tó yẹ, nínú èyí tátin sisẹ́ àgbédìde fún àwọn ilésẹ́ tón pawó wọlé fún ìjọba, àmúgbòrò isẹ́ ajé àti lílọgere ọkọ̀ lójú pópó, ó wá korò ojú sí bí ọ̀pọ̀ ìpínlẹ̀ kò se mójútó àtò ìlú lọ́nà tó yẹ.

Nínú ọ̀rọ̀ ìkíni kábọ rẹ̀, alága àjọ náà, ọ̀gbẹ́ni Ọlajide Adeyẹmọ sọ pé, àwọn on amáyé dẹrùn nílu bàdàn nílò àtúnse àti àtúntò ní kọ́mọ́nkía kó lè mú àgbéga bá ètò ọ̀rọ̀ ajé nílu ìbàdàn àti ìpínlẹ̀ Ọyọ lápapọ̀.

Lásìkò tón síde ìpàdé àpérò ọ̀hún olórí àwọn òsìsẹ́ nípinlẹ̀ Ọyọ, arábìnrin Aminat Agboola, tẹnumọ́ pé, ìsèjọba Gómìnà Seyi Makinde yo sisẹ́ tọ́ọ̀, sisẹ́ àmúlò lílo àtóò tó jẹ́ ti ìlú bàdàn. 

Ìpàdé àpérò èyí tí àjọ tón mójútó àtò ìlú, ńse lọ́wọ́, ńtẹ̀síwájú lóni ní gbọ̀ngan ńlá àpérò, nílé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ìbàdàn.

Kẹmi Ogunkọla/Famakin

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *