Yoruba

Gómìnà Tuntun Sèlérí Láti Mú Àgbéga bá Ètò Ìròyìn

Gómìnà Ọyọ tílu sẹ̀sẹ̀ dìbò yàn, ọ̀gbéni Seyi Makinde ti sọ pé òfin tó fàyè sílẹ̀ fáwọn èyàn láti ní ẹ̀tọ́ sí ìròyìn àtọ̀rọ̀ tónlọ se pàtàkì àti wípé yo mu àgbéga bá káwọn èyàn ma dásí ètò ìsèjọba nípinlẹ̀ yi.

Ó sọ̀rọ̀ yi nígbàtí ikọ̀ ìgbìmọ̀ alásẹ ilésẹ́ Radio Nigeria, èyí tí ọ̀gágba fún ilésẹ́ náà ẹkùn Ìbàdàn, Àlhájì Muhammed Bello lé wájú rẹ̀, lọ ki kú oríre ìjáwé olúborí nínú ètò ìdìbò sípò Gómìnà tó wáyé lọ́jọ́ kẹsan osù yi, nílé rẹ̀ tó wà ní Ìkọ́làbà nílu Ìbàdàn.

Ọgbẹni Makinde sọ pé ìsèjọba òun, nígbà tóbá bẹ̀rẹ̀ yo fàyè gba àwọn arálu láti lo ẹ̀tọ́ wọn lórí ìròyìn àtọ̀rọ̀ tónlọ, tí wọ́n yo fi le kópa tó jọjú nínú ìdàgbàsókè Ìpínlẹ̀ Ọyọ.

Ọgbẹni Makinde wá gbóríyìn fún ilésẹ́ Radio Nigeria fún bí wọ́n se sàtìlẹyìn fún gbogbo ẹgbẹ́ òsèlú lásìkò ìpòlongo ibò tó si tún bèrè fún ìbásepọ̀ tó gúnmọ́ nínú ètò ìsèjọba tónbọ̀.

Iyabo Adebisi/Kemi Ogunkọla

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *