Yoruba

Ọga àgbà Radio Nigeria gba òsìsẹ́ nímọ̀ràn lórí ìnákúna

Àkókò ayọ̀ àti ìdùnú lójẹ́ fún àwọn òsìsẹ́ lẹ́ka tó ńsàkóso nílesẹ́ Radio Nigeria ẹkùn ìbàdàn nígbàtí wọ́n kórawọn jọ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún anu rẹ̀ fódidi ọdún kan gbáko.

Akọ̀ròyìn wa jabọ̀ pe, ètò náà tówáyé ní gbàgan Studio 1 nílesẹ́ náà, làwọn ìgbìmọ̀ olùdarí ilésẹ́ ọ̀hún.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, olùdarí àgbà nílesẹ́ FRCN, ẹkùn ìbàdàn Àlhájì Mohammed Bello rọ àwọn òsìsẹ́ ìjọba láti ma se ohun gbogbo níwọ̀n tuwọ̀n sì.

Nígbà tó ńsọ̀rọ̀ ìkíni kábọ, igbákejì olùdarí lẹ́ka ètò àkóso, ọ̀mọ̀wé Adenikẹ Arẹmu tọ́kasí pé, ẹ́ka náà ti ńfi ìgbàgbogbo se ohun tóyẹ, tósì ńsisẹ́ rẹ̀ kójú-òsùwọ̀n.

Bákanà àwọn tó gba àmìn ẹ̀yẹ kòle pa ayọ̀ wọn mọ́ra níbi ètò náà.

Ẹwẹ, gbogbo àwọn òsìsẹ́ ẹ̀ka náà jó, wọ́n yọ́ọ̀ pẹ̀lú oníruru orin, tí wọ́n sì fasọ́ọ̀ kana sàmì ìdúpẹ́ wọn ọ̀hún.

Kẹmi Ogunkọla/Ibomor

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *