September 21, 2020
Health

Ilé ìgbìmò asofin daba kí wọ́n ya àwọn tó rìnrìn àjò bò láti ilè China

Ilé ìgbìmò asofin àgbà ile yi ti késí ilé isẹ ìjọba lórí ọ̀rọ̀ ìrìn àjò ofurufu láti rii dájú wípé gbogbo àwọn tí wọ́n bá ńwọlé láti orílè èdè China ni wọ́n yà sọto nílé wọn fún o kéré tán ọ̀sẹ̀ méjì kí wọ́n tó bèrè sì nii darapo mọ àwọn ará ìlú.

Ònígbowó àbá yi tíì tún ṣe alága ìgbìmò teekoto ilẹ̀ lórí àwọn àìsàn tó le tatare, Chukwuka Utazi náà tún nawoja ìpè yí sí gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń rìnrìn àjò bò láti ìlú tí wọ́n ti fojú wina ajakale àrùn Corona òún.

Ó tẹnumo ìdí tó fi ṣe pàtàkì fún àwọn ọmọ orílè èdè China tí wọ́n ńgbé nílè yíì tí wọ́n rìnrìn àjò fún ọdún tuntun ìlú wọn láti wà láàyè ọ̀tọ̀ fún ọ̀sẹ̀ méjì ó kéré tán kí wọ́n tó darapo mọ àwọn ọmọ ilẹ̀ yí láti dènà ìtànkalẹ àrùn asekupani yí.

Senator Utazi gba àwọn ọmọ ilẹ̀ yí tí wọ́n fẹ́ rìnrìn àjò lọ sáwọn orílẹ̀ èdè Asia láti dáa dúró náà títí tí kòkòrò àrùn Corona tó ń jà rairai yio fi di ohun ìgbàgbé.

Adesanya/Dada Yemisi

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *