Yoruba

Ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ gùnlé abala kejì isẹ́ àkànse iná ojú pópó nílu Ògbómọ̀sọ́

Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, onímọ̀ẹ̀rọ Seyi Makinde ti gùnlé abala kejì isẹ́ àkànse ìpèsè iná ojú pópó àtàtúnse pápá ìseré ilé-ẹ̀kọ́ gíga fásitì ìmọ̀-ẹ̀rọ Lautech, tó wà nílu Ògbómọ̀sọ́ alaimọye Billiọnu naira.

Ẹnu àbáwọlé kejì ilé-isẹ́ gíga fasity ọ̀hún, leto náà ti wáyé nílu Ògbómọ̀sọ́.

Abala kejì isẹ́ àkànse náà tó jẹ́ kilometer ọgbọnlerugba ó dín diẹ, ni Gómìnà Makinde sọ pé, yóò gbà tó billiọnu mejidinlọgbọn naira àti diẹ èyí tí agbasẹ́ se tó wà nídi isẹ́ àkànse ọ̀hún yóò na látọwọ́ ara rẹ̀, pẹ̀lú èròngbà sísan padà fódidi ọdún méje.

Kò sài fi kákàlé rl pé, èróngbà isẹ́ àkànse náà ni láti fi mágbega bá ètò ọrọ̀ ajé ilẹ Ògbómọ̀sọ́ àti mímúàgbéga bá ètò ìrìnà àwọn tó n sàmúlò ojú pópó, papa jùlọ àwọn akẹ́kọ́ọ̀ ilé-ẹ̀kọ́ gíga fasity náà.

Nínú ọ̀rs tiẹ, asojú ilé-isẹ́ agbasẹ́ tó wà nídi isk àkánse náà, onímọ̀ẹ̀rọ Abdul-Ramọn Odunlawọ tọ́kasi pé, gbèdéke osù mẹ́fà sósù mẹ́san labala kejì isẹ́ àkànse náà yóò parí.

Wojuade  

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *