Àjọ tó rísí owó ìrànwọ́ àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga TETFUND ti fi ìrètí hàn, wípé, owó ti yóò jẹ́ yíyá sóòtó gẹ́gẹ́ bí owó ìrànwọ́ isẹ́ ìwádi fọ́dún 2022 yóò tóò billiọnu mẹ́wa naira.

Akọ̀wé àgbà àjọ TETFUND, Ọ̀jọ̀gbọ́n Suleiman Bogoro níì ìgbìmọ̀ alásẹ àjọ ohun buwọlu owó tó léní billiọnu mẹ́jọ náira gẹ́gẹ́ bí owó ìrànwọ́ isẹ́ ìwádi fọ́dún 2021, ó sọ èyí bi ìpàdé kan.

Ó tọ́kasi pé, owó náà pín sí ọ̀nà méjì, tí ilé-ẹ̀kọ́ gíga àti ti ise ìwádi.

Ọ̀jọgbọn Bogoro ní lọ́dún 2019, billiọnu márun náirà lójẹ́ yíyá sọ́tọ̀ fún isẹ́ ìwádi, ti billiọnu méje abonara sijẹ yíyà sọ́tọ̀ lọ́dún 2020 kótodípé milliọnu mkjọ àbọ̀ sí jẹ́ yíyá sọ́tọ̀ lọ̀dún 2021.

Ó fikun pé owó ìrànwọ́ isẹ́ ìwádi jẹ́ ọ̀kan lára ìlànà tíjọba gbékalẹ̀ nípasẹ̀ àjọ TETFUND, láti sàtìlẹyìn fún isẹ́ ìwádi àwọn ilé ẹ́kọ́-gíga láti sàseyọrí lẹ́ka ìwádi ìmọ̀ science àti ìmọ̀ ẹ̀rọ.

Net/Elizabeth Idogbe

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *