News Yoruba

Bánki Àpapọ̀, CBN, Pàse Kíwọ́n Gbé Àsùnwọ̀n Àwọn Olùdókowò Orí-Ẹ̀rọ Ayélujára.

.Àwọn tó ńse ìdókowò lórí ẹ̀rọ ayélujára tamọ̀sí Criptocurrency ni wọ́n ti bèrè si ńse ìdókowò wọn lábẹ́nú yàtọ̀ sí èyí táwọn èèyàn mọ̀tẹ́lẹ̀, nítorí àsẹ bánki àpapọ̀ ilẹ̀ yíì, pé káwọn ilé-ìfowópamọ́ gbé àsùwọ̀n àwọn olùdókowò ohun tì páà.

Olùdásílẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ kan, tíwọ́n ti ńkọ́ nípa ìdókowò wóòyi Rume Ophi, lána òde yíì sọpé, àwọn ilé-ìfowópamọ́ tí kansi àwọn olùdókowò Criptocurrency lórí àsẹ tí ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ páà.

Lọ́jọ́ ẹtì ni ilésẹ́ bánki àpapọ̀ ilẹ̀ yíì pàsẹ fáwọn ilé ìfowópamọ́ àti àwọn àjọ tó ni ńkan se pẹ̀lú ìdókowò láti gbé àsùwọ̀n àwọn tó ńse ìdókóòwò orí ẹ̀rọ ayélujára, Criptocurrency ti páà.

Ó ní pẹ̀lú ìgbésẹ̀ yíì àwọn olùdókowò ti ba si se okóòwò wọn lọ́nà míran yàtọ̀ sí àwọn àtẹ táwọn èèyàn mọ tẹ́lẹ̀ torípé wọ́n o le san owó láti pasẹ̀ àwọn àjọ tóní ǹkan se pẹ̀lú ìdókowò mọ.

Net/Idogbe

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *