Yoruba

Òjísẹ́ Ọlọ́run gba ìmọ̀ràn lórí ìfọkànsì

Bísọ̀bù ìjọ Victory International Church, nílu ìbàdàn, Àlúfà Taiwo Adelakun ti gba ọmọlẹ́yìn Kristi níyànjú láti jẹ́ olùgbọ́ràn, kí wọ́n se fi tọkàntara se isẹ́ Ọlọ́run, kí wọ́n ba lè gbádùn oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀.

Bisọbu Adelakun sọ̀rọ̀ ní níbi ìpàgọ̀ òjọ̀dún ìjọ His Pavilion Christian Centre, tó wà ní Àkóbọ̀ nílu Ìbàdàn.

Bisọbu na sàpèjúwe oore-ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn tí ọ́rọrùn fún ẹ̀dá láti fi yi ayé rẹ̀ padà, ó sì rọ àwọn onígbàgbọ́ láti sáà fún ẹ̀sẹ̀.

Àlúfà àgbà nínú ìjọ His Pavilion Christian Centre, Ẹniọwọ Niyi Dahunsi sàlàyé pé, oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun se kókó, bí èèyàn bá ń fẹ́ àseyọ́rí, Ó wá rọ́ọ̀ àwọn Kristiéni láti ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

Ìpàgọ́ na ni wọ́n fi sààmì àjọ̀dún ọdún kérin ìjọ His Pavilion Christian Centre.

Kẹmi Ogunkọla/Osas

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *