Àgbáríjọpọ̀ ẹgbẹ́ àwọn òsìsẹ́ lórílẹ̀èdè yi NLC, ti sọ pé, òun kò mọ ǹkankan nípa pé, ẹgbẹ́ olùkọ́ fásitì ASUU, ti pín sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ, ó ní òhun tóun mọ̀ ni pé, ẹgbẹ́ ASUU, kansoso lówà.

Àarẹ ẹgbẹ́ òsìsẹ́ NLC, ọ̀gbẹ́ni Ayuba Wabba sọ pé, òhun mọ̀ pé, àwọn kan ti gbìyànjú nígbàkanrí láti pín ẹgbẹ́ nà si yẹ́lẹyẹ̀lẹ sùgbọ́n tí èròngbà wọn kojọ tó si jákulẹ̀ nígbà na.

Nígbà tóun na ń sọ̀rọ̀, akọ̀wé àjọ NLC, ọ̀gbẹ́ni Emma Ugbaja, sọ pé lóòtọ ni oníkákálùkù  ló ní ẹ̀tọ́ láti dá ẹgbẹ́ tó wúù sílẹ̀, sùgbọ́n òfin tó gbé ẹgbẹ́ òsìsẹ́ kalẹ̀ sọ pé, ó ní àwọn ìgbésẹ̀ tó yẹ kí wọ́n gbé, kí wọ́n tó lè dá ẹgbẹ́ yoowu sílẹ̀, ni tí ẹgbẹ́ NLC, ẹgbẹ́ ASUU kan soso lárin mọ̀ pé ówà.

Kẹmi Ogunkọla/Ibomor

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *