News

Àwọn Gómìnà lẹ́kùn gúusù ìwọ̀orùn sàpérò lórí ètò àabò

Àwọn Gómìnà mẹ́fàfà láti ẹkùn gìwọ̀orùn gúsù ilẹ̀ yi ni wọ́n se pàsé pọ̀ lána, láti gbógun ti ìwà ọ̀daràn lẹ́kùn náà.

Wọ́n tẹnumọ sísàmúlò ọlọ́pa láwọn Ìpínlẹ̀ àti lẹ́kùn jẹkù láti mú kíwà ọ̀daràn tó fẹ́ ma pọ̀si, wá sópin pátápátá yíká ilẹ̀ yí.

Àwọn Gómìnà ló fìdí ọ̀rọ̀ yi múlẹ̀ níbi ìpàdé àpérò, ọlọ́jọ́ mẹ́ta tó bẹ̀rẹ̀ nílu bàdàn olúlu ìpínlẹ̀ Ọyó.

Níbi ìpàdè àpérò náà ni àwọn Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọyọ, Òndó, típínlẹ̀ Èkó, Èkìtì, Ọsun àti Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ògùn wá.

Nígbà tó n sọ̀rọ̀ lórúkọ àwọn Gómìnà, Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ, omímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde sọ pé kòsí àní-àní pé àwọn Gómìnà mẹ̀fàfà ti setán láti sisẹ́ papọ̀ fi múkí àbò ẹ̀mí àti dúkia gbópan si.

Ó sàpèjúre ipò tétò ọ̀rọ̀ àbówà gẹ́gẹ́bí èyí tó ńfẹ́ àmójútó, tósì tẹnumọ pé ìpàdé àpérò náà wáyé lásìkò tó yẹ.

Kẹmi Ogunkọla/Famakin

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *