Yoruba

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ fọwọ́sí ìyànsípò ìgbìmọ̀ ìjọba ìbílẹ̀

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde tifọwọ́sí ìyànsípò ìgbìmọ̀ tí yio ma se kòkáárí ìjọba ìbílẹ̀ tófomọ́ àjọ ìgbòkè gbodò ọkọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ọyọ.

Nínú àtẹ̀jáde kan t;i akọ̀wé ìròyìn àgbà sí Gómìnà, ọ̀gbẹ́ni Taiwo Adisa fisíta sọpé ọ̀mọ̀wé Rẹmi Ayodele ni alága àjọ tón rísí ọ̀rọ̀ ìjọba ìbílẹ̀ tí alága ìgbìmọ̀ àjọ ìgbòkè gbodò ọkọ̀ síjẹ mọ́gàjí Akin Fagbemi, tí ọ̀gbẹ́ni Kunle Yusuf jẹ́ amúgbàlẹ́gbẹ àgbà lórí ọ̀rọ̀ ìdàgbàsókè.

Àtẹ̀jáde na tún dárúkọ àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ àjọ tón rísí ọ̀rọ̀ ìjọba ìbílẹ̀ lára wọn ni Àlhájì Oyesina Oyedele ọmọ ìgbìmọ̀ lẹ́kunrẹ́rẹ́, ọ̀gbẹ́ni John Ọkẹ ọmọ ìgbìmọ̀, Àlhájì Ọkẹ Taiwo àti Arábìnrin Nikẹ Arẹwa.

Idogbe

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *