Ibùdóìgbafẹ́ ìjọba àpapọ̀ tó wà nílu Ọyọ, ni wọ́n ti fi àmìn ẹ̀yẹ dá àwọn òsìsẹ́ tó sẹ̀sẹ̀ gba àgbéga lẹ́nu isẹ́ lọ́lá èyí tó yàtọ̀ gédégbé sí báwọn òsìsẹ́ kan séngba ìwé àgbéga tẹ́lẹ̀rí tí wọ́n yo sì fipamọ́.

Akọ̀ròrìn ilésẹ́ Radio Nigeria fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pe, ìgbésẹ̀ tuntun yi lówà níbamu pẹ̀lú bí ibùdó náà seti wà lábẹ́ àkoso ìjọba àpapọ̀ báyi.

Gẹ́ǵ́ẹ́bí olùdarí fún ibùdó ìgbafẹ́ náà, ọ̀gbẹ́ni Henry Ndoma se sọ wípé ọ̀nà tuntun yi ni yo jẹ kóríyá fáwọn òsìsẹ́ láti lè túnbọ̀ se dada si lẹ́nu isẹ́ wọn.

Ọgbẹni Ndoma sọ síwájú pé, ní lọ́lọ́ ìwà ọ̀daràn bi pípẹran lọ́nà àitọ́, àti kíkó ẹran máàlu jẹ̀ nínú ọgbà lọ́nà tí kò bófinmu lóti dínkù jọjọ, àti wípé ìbásopọ̀ tó lóòrin tiwà láarin ibùdó ìgbafẹ́ náà àtàwọn agbègbè ibẹ̀.

Kemi Ogunkọla

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *