Yoruba

Ìpínlẹ̀ Ògùn bojúwò ìbéére lórí àgbékalẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ fásitì

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ògún sọ pé, òhun ti ń bojúwò ìbéére àwọn èèyàn ẹkùn ìdìbò àrigbùgbù àti ìwọ̀orùn ìpínlẹ̀ Ògùn, tó wọ́n ní àwọn na ń fẹ́ kí iléékọ gíga fásitì wà ní agbègbè àwọn.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn, Dapọ Abiọdun ló kéde ọ̀rọ̀ yi nílu Abẹokuta, níbi tó ti sàlàyé fún àwọn asojú ẹkùn dìbò méjèjì pe, òun ti gbọ́ nípa ohun tí ń wọ́n bèèrè fún, pé àwọn fẹ́ iléékọ gíga fasiti ní ẹkùn ìdìbò àwọn lẹ́kùn, nítorípé ìjọba kò fi bẹ lọ́wọ́ lapọ.

Gómìnà Abiọdun wá mú dáà èèyàn ìpínlẹ̀ na lójú pé, ìjọba yo tubọ̀ sètò ti yo mú kí ìkọ́nilẹ́kọ àti ìkẹ́kọ rọrùn, àti pé ètò àtúnkọ́ ẹ̀kọ́ yo wa fún àwọn olùkọ́ pẹ̀lú.

Kẹmi Ogunkọla/Akanpa

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *