Yoruba

Ilésẹ́ ológun fẹ́ gùnlé ètò ìdánimọ̀ láti pinwọ́ ìgbésùmọ̀mí

Lákokò yíì lọ, àwọn ọmọ orílẹ́dé yíì yóò nílò láti máà mú káàdi ìdánimọ̀ wọn káakiri láti lè fihan àwọn ọmọológun ilẹ̀ yíì se gùnlé ìgbésẹ̀ míma yẹ àwọn araalu wò, lábẹ́ ètò tuntun kan nílẹ̀ sẹ́ ológun ọ̀hún èyí tíwọ́n gbé orúkọ rẹ̀ ni, Operation Positive Identification.

Gẹ́gẹ́ bọ́ga àgbà ológun ilẹ̀ yíì, ọ̀gágun àgbà Tukur Buratai se sọ́ọ́di mímọ̀ pé, àwọn tọ́rọ̀ tétò náà kan gbọ̀ngbọ̀n ni àwọn tírìn wọn mú ìfura lọ́wọ́.

Ó sàlàyé pé, ikọ̀ náà yóò máà lé àwọn agbésùmọ̀mí kúrò láwọn ẹkun kan tíwọ́n lánfani láti máà fara soko si.

Ọgagun àgbà Buratai tó fìdí ọ̀rọ̀ yíì múlẹ̀ lákokò ìfilọ́lẹ̀ ètò kan nílé sẹ́ ọmọ ológun ọ̀húnèyí tówà lẹ́kùn àríwá ìlàoorùn ilẹ̀ yíì, làwọn yóò nawọ́jà rẹ̀ dáwọn ẹkùn kọ̀ọ̀kan tó ń bẹ nílẹ̀ yíì.

Kò sài fikun pé, ilé isẹ́ ọmọ ológun náà ti setán láti wagbò dẹ́kun fáwọn ikọ̀ ọlọ́tẹ̀, àwọn ajínigbé, adigunjalè, tó fimọ́ ìjà ẹlẹ́yàmẹ̀yà àtàwọn ìwà ọ̀daràn min-in.

Kẹmi Ogunkọla/    

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *