Yoruba

Ijoba ipinle ati ibile yio janfani ekunwo ori oja – Babatunde Fasola

Alakoso fun ise ode on ilegbe lorile ede yii, Babatunde Fashola ti soo di mimo pe ida marundinlaadorin owo ori oja ti won ba pa ninu eto isuna odun 2020 ni won yio da pada fawon ipinle ati ijoba ibinle lati wa fisan owo osu ati idokowo leka nkan amayederun.

Gegebi ogbeni Fasola ti se wi, ida meedogun toku ni yio lo sodo ijoba apapo fun idagbasoke ohun amayederun.

Alakoso naa lo salaye oro yii ninu atejade ti ilese ijoba apapo te sita nilu Abuja, leyi to sapejuwe aba eto isuna odun 2020 gege bi eyi ti yio gbe awon eeyan ati ipinle laruge.

O salaye pe aba eto isuna naa yio mu idagbasoke tesiwaju fun ipinle ti yio si mu agbega ba igbe aye enikokan. O war o gbogbo aralu pe ki won foju sunukun wo aba eto isuna naa yato fun iye owo to wa mbe.

Yemisi Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *