Yoruba

Owọ́ palaba ọ̀daràn kan segi nilu Ọ̀yọ́

Díẹ̀ lókun kí afurasì ọ̀daràn darandaran kan tíwọ́n poruko ẹ ní Umoru Aliyu salo pátápátá ko tó di powo àwọn figilante tẹ nínú igbó tó sá pamó sí, lẹ́yìn tí wọ́n ní o sá ọkùnrin àgbè kan lágbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Afijio.

Ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yí lagbo pé ó ṣẹlẹ̀ lale àná labule àgó Ọ̀yọ́, tọrọ náà sí gbóná tó bẹ lára àwọn àgbè kan tíwọ́n fi gbìyànjú láti gbẹ̀san lára àwọn darandaran yokù lágbègbè òun.

Adarí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ figilante ńipinle Ọ̀yọ́, alàgbà Sunday Olajide tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ na lélẹ̀ làwọn ti fa afurasì bororo oun lé àwọn Ọlọpa saasi tówà nilu Ọ̀yọ́ lọ́wọ́.

Bakana lagbo pé ọkùnrin àgbè to kágbáko lọ́wọ́ darandaran òun wà lẹsẹ kan aiye ẹsẹ kan ọrun báyi nílé ìwòsàn aladani kan nilu ilora níbi tó ti ń gbà ìtọ́jú.

Bẹ́ẹ̀ sì làwọn Ọlọpa àtàwọn figilante ti kọjá lọ sagbegbe tísele òun ti ṣẹlẹ̀ láti dènà wàhálà tó le soyo.

Ogunkola /Oguntona 

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *