Yoruba

Onímò ìlera gbamoran lórí àrun Lassa

Onímò nípa isegun kan, Dókítà Olajide Oladipupo ti niki àwọn ènìyàn mú imotótó lókunkúndùn láti leè dènà àìsàn ibà ọ̀rẹ̀rẹ̀.

Dókítà Oladipupo sọ̀rọ̀ yi nínú iforowero pẹ̀lú akoroyin agbègbè àti ìgberíko nilu Ìbàdàn.

Ó fi aidunu rè hàn sí bí àwọn èèyàn kìí se kọbiara sí ìlera wọn ní paapajulo imotótó àyíká wọn leyi tó ní ó ṣe kókó fún ìlera.

Ó wá ro wọ́n láti máa da àwọn ìdọ̀tí àti ẹ̀gbin wọn nù lọ́nà tó yẹ. 

Dókítà Oladipupo wá gba àwọn ènìyàn lamoran wípé tí wọ́n bá kéfín àwọn àpẹrẹ bí ṣíṣe igbonse léraléra, inú kíkan, kí ẹ̀jẹ̀ má yọ nimú àti bíbi èébì ẹ̀jẹ̀ kí wọ́n tètè lọ sí àwọn ilé ìwòsàn fún itọju tó péye.

Kemi Ogunkọla/Taiwo Akinọla

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *