Gómìnà Oluwarotimi Akeredolu ti ìpínlẹ̀ Òndó ti rọ ọ̀gá àgbà ọlọ́pa nílẹ̀ yí láti túbọ̀ kó àwọn ọlọ́pa àti àwọn oun èèlò ìgbófin ró wá si ìpínlẹ̀ náà láti léè kojú ìwà ìjínigbé tó ti ńdi gbọnmọgbọn nípinlẹ̀ náà.

Ó sọ̀rọ̀ àrọwà yi nílu Àkúrẹ́ níbi ìfilọ́lẹ̀ ìgbìmọ̀ tí yíò máà rísí ọ̀rọ̀ ọlọ́pa agbègbè.

Gómìnà ẹnití ó ní bí àwọn ìgbésẹ̀ yi bá di síse, àwọn ajínigbé yíò súnra kì.

Ó ní kòsí àníani wípé ilé isẹ́ ọlọ́pa nípinlẹ̀ náà ńsisẹ́ takuntakun láti kase irú ìwà bẹ́ẹ̀ nílẹ̀ amọ, tí ó ní wọ́n sì tún níse láti séè síì.

Gómìnà Akeredolu ẹnití ó bu ẹnu àtẹ́ lu bí ìwà ìjínibgé se ńpọ̀ síì wà ti ìmọrírì rẹ̀ hàn sí ìjọba àpapọ̀ àti ọ̀gá àgbà ọlọ́pa lórí èróngbà wọn lórí ọlọ́pa àgbègbè .

Ó ní ìgbésẹ̀ yi yíò túbọ̀ ró ètò ààbò ẹ̀mí àti dúkia àwọn ènìyàn lágbára síì, ó wá rọ ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹẹdógún ọ̀ún láti sisẹ́ bíì isẹ

Oluwayẹmisi Dada

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *