Education

Sísí ilé ẹ̀kọ́ padà, alákoso sọ ìlànà a ńtẹẹlé

Alakoso fétò ẹ̀kọ́ kejì, Emeka Nwajiuba ti sọ wípé àwọn ilé ìwé léè sílèkùn padà nílẹ̀ yí lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ka òfin tó de lílọ bíbọ̀ láàrin àwọn ìpínlẹ̀ nílẹ̀.

Alákoso ọ̀ún sọ̀rọ̀ yí níbi ìjábọ̀ ojoojúmọ́ lórí ibi tí ǹkan dé dúró lórí ọ̀rọ̀ covid 19 tí ìgbìmọ̀ amúséyá ìjọba àpapọ̀ nílu Abuja.

Ó ní ìjọba kò tíì sọ pàtó tí wọn yíò si àwọn ilé ìwé padà nítorí ilé isẹ́ ìjọba lórí ẹ̀kọ́ kò ní fi àwọn ènìyàn sínú ewu.

Ọgbẹni Nwajiuba ní wọn yíò si àwọn ilé ìwé padà nígbàtí wọ́n bá ri pé àabò wà fún àwọn akẹ́kọ.

Lósù kẹ́ta ọdún yi ni ìjọba àpapọ̀ gbé àwọn ilé ìwé tì pa láti léè dènà ìtànkélẹ̀ àrùn covid 19.

Oluwayemisi Dada

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *