Ìgbìmọ̀ alásẹ ìjọba àpapọ̀ ti buwọ́lu owó tó lé ní áàdọ́jọ billiọnu naira fún síse àwọn òpópónà méje káàkiri ilẹ̀ yí.

Alákoso fọ́rọ̀ isẹ́ òde àti ilégbe, ọ̀gbẹ́ni Babatunde Fashọla ló sọ̀rọ̀ lórí àbájáde ìpàdé wọn nílu Abuja.

Alákoso ní àwọn ọ̀nà náà yíò pèsè isẹ́ fún àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ènìyàn.

Gẹ́gẹ́bí ó se sọ, àwọn òpópónà yi nínú sísọ òpópónà Àkúrẹ́ sí Adó-Èkìtì àti ojú ọ̀nà Ukana-Akpautong sí Ikọt Ntuen nípinlẹ̀ Akwa Ibọm.

Ọgbẹni Fashọla ní ìgbìmọ̀ alásẹ ti fọwọ́sí gbígbé isẹ́ òpópónà náà fún agbasẹ́se lábẹ́ àbá ìsúná ọdún 2020.

Oluwayẹmisi Dada

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *